Ohun Tí O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn
Ile Ìṣọ́ June 15
“Ǹjẹ́ o gbà pé ọmọ títọ́ kò rọrùn láyé òde òní? [Jẹ́ kó fèsì.] Gbọ́ ohun tí Bíbélì sọ láti fi àwọn òbí lọ́kàn balẹ̀ pé wọ́n lè ṣe iṣẹ́ ọmọ títọ́ láṣeyọrí. [Ka Òwe 22:6.] Ìmọ̀ràn tó lè ran àwọn òbí lọ́wọ́ láti ṣe èyí wà nínú ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ yìí.”
Ile Ìṣọ́ July 1
“Nígbà tí nǹkan ìbànújẹ́ bá ṣẹlẹ̀, ọ̀pọ̀ máa ń ronú pé bóyá ni Ọlọ́run tiẹ̀ bìkítà nípa wa àti pé bóyá ló ń rí ìnira wa. Ǹjẹ́ o ti ronú nípa ìyẹn rí? [Jẹ́ kó fèsì.] Ìwé ìròyìn yìí ṣàlàyé bí Ọlọ́run ṣe ń fi hàn pé òun bìkítà nípa wa lónìí, àti bó ṣe fi ìpìlẹ̀ lélẹ̀ láti mú gbogbo ìnira kúrò.” Ka Jòhánù 3:16.
Jí! July 8
“Lójú ọ̀pọ̀ èèyàn, ìgbà èwe jẹ́ àkókò ayọ̀ àti àkókò ìṣòro, ǹjẹ́ ìwọ náà ò gbà bẹ́ẹ̀? [Jẹ́ kó fèsì.] Ìwé ìròyìn yìí sọ̀rọ̀ lórí àwọn ìyípadà tó máa ń wáyé nínú ìgbésí ayé àwọn ọ̀dọ́langba. Ó tún fúnni láwọn ìmọ̀ràn ọlọgbọ́n díẹ̀ tó lè ràn wọ́n lọ́wọ́ láti lo ìgbà èwe wọn lọ́nà tó dára jù lọ.” Ka Oníwàásù 12:1.