Ohun Tí O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn
Ile Ìṣọ́ May 15
“Ǹjẹ́ o tíì ronú nípa bóyá ohun tí àwa ẹ̀dá èèyàn ń ṣe lórí ilẹ̀ ayé kan Ọlọ́run? [Jẹ́ kó fèsì.] Wo bí ìṣesí wa ṣe lè rí lára Ọlọ́run. [Ka Òwe 27:11.] Ìwé ìròyìn yìí sọ̀rọ̀ nípa àwọn èèyàn kan tí wọ́n múnú Ọlọ́run dùn, ó sì ṣàlàyé bí àwa náà ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀.”
Ile Ìṣọ́ June 1
“Àwọn èèyàn kan rò pé kò pọn dandan láti jẹ́ ara ètò ẹ̀sìn kan ká tó lè jọ́sìn Ọlọ́run. Ǹjẹ́ o ti ronú nípa ìyẹn rí? [Jẹ́ kó fèsì.] Ìwé ìròyìn yìí ṣàyẹ̀wò bí Ọlọ́run ṣe bá àwọn èèyàn lò láwọn ìgbà tó ti kọjá. Ó tún ṣàlàyé ohun tí jíjọ́sìn Ọlọ́run ní òtítọ́ túmọ̀ sí.” Ka Jòhánù 4:24.
Jí! June 8
“Ìmọ̀ ìṣègùn ti tẹ̀ síwájú gan-an nínú gbígbógun ti àìsàn, àmọ́ ṣé o rò pé ìgbà kan ń bọ̀ tí àìsàn á dàwátì láyé? [Jẹ́ kó fèsì.] Ìwé ìròyìn yìí ṣàlàyé pé lọ́jọ́ kan gbogbo èèyàn tó wà lórí ilẹ̀ ayé á ní ìlera tó jí pépé ní ìmúṣẹ ìlérí yìí.” Ka Aísáyà 33:24.
“Ọ̀pọ̀ èèyàn lónìí ló ní ìṣòro ìnìkanwà. Wọ́n máa ń wò ó pé àwọn èèyàn pa àwọn tì. Ǹjẹ́ èyí kì í dunni gan-an? [Jẹ́ kó fèsì. Lẹ́yìn náà ka Sáàmù 25:16.] Ìwé ìròyìn Jí! yìí sọ àwọn àbá tó lè ràn wá lọ́wọ́ láti gbógun ti ìṣòro ìnìkanwà.”