Ohun Tó O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn
Ile Iṣọ May 15
“Báwo lo ṣe máa dáhùn ìbéèrè tó wà lẹ́yìn ìwé ìròyìn yìí? [Ka ìbéèrè tó wà lẹ́yìn ìwé ìròyìn, lẹ́yìn náà jẹ́ kó fèsì.] Bíbélì ti jẹ́ ká mọ ìdí tá ò fi gbọ́dọ̀ sọ̀rètí nù. [Ka Mátíù 6:9, 10.] Ìwé ìròyìn yìí ṣàlàyé ọ̀nà tí Ìjọba Ọlọ́run máa gbà mú ìfẹ́ Jèhófà ṣẹ lórí ilẹ̀ ayé.”
Ile Iṣọ June 1
“Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ lè jẹ́ pé ojoojúmọ́ là ń gbọ́ ìròyìn nípa àwọn amòòkùnṣìkà ẹ̀dá. [Mẹ́nu ba ìwà ibi kan tó ṣẹ̀ṣẹ̀ wáyé lágbègbè yín.] Ǹjẹ́ ó tiẹ̀ ti ṣe ẹ́ rí bíi pé ẹni àìrí kan wà níbì kan tó ń súnná sí báwọn èèyàn ṣe ń hùwà ibi? [Jẹ́ kó fèsì. Kó o wá ka Ìṣípayá 12:12.] Ìwé ìròyìn yìí ṣàlàyé bá a ṣe lè dáàbò bo ara wa.”
Jí! Apr.–June
“Lọ́pọ̀ ibi láyé, àwọn èèyàn ti kíyè sí i pé ìwà rere ti ń jó rẹ̀yìn. Ṣéwọ náà rí i bẹ́ẹ̀? [Jẹ́ kó fèsì.] Àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì làwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lákòókò wa yìí ń mú ṣẹ. [Ka 2 Tímótì 3:2-4.] Ìwé ìròyìn yìí jẹ́ ká mọ ohun tó fà á tí ìwà rere fi ń jó rẹ̀yìn, ó sì jẹ́ ká mọ ohun tó máa yọrí sí fọ́mọ aráyé.”
“Ọ̀pọ̀ ló ń sọ pé Kristẹni làwọn. Ta lo rò pó yẹ ká pè ní Kristẹni? [Jẹ́ kó fèsì.] Gbọ́ ohun tí Jésù sọ nínú ẹsẹ Bíbélì yìí. [Ka Jòhánù 15:14.] Àpilẹ̀kọ yìí fi ohun téèyàn gbọ́dọ̀ ṣe hàn kó tó lè fi gbogbo ẹnu sọ ọ́ pé Kristẹni lòun.” Fi àpilẹ̀kọ tó bẹ̀rẹ̀ ní ojú ìwé 28 hàn án.