Ohun Tó O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn
Ilé Ìṣọ́ May 1
Ka Mátíù 24:3. Lẹ́yìn náà sọ pé: “Àwọn kan rò pé òpin ilẹ̀ ayé wa ni ìbéèrè yìí dá lé lórí. Ǹjẹ́ o rò pé ayé yìí máa pa run? [Jẹ́ kó fèsì.] Ìdáhùn Jésù jẹ́ ká mọ̀ pé ayé yìí kò ní pa run, àmọ́, òpin máa dé bá nǹkan kan. Àpilẹ̀kọ tó wà lójú ìwé 16 ṣàlàyé síwájú sí i lórí èyí.”
Jí! April–June
Ka Diutarónómì 30:19, 20. Lẹ́yìn náà, kó o wá béèrè pé: “Ṣé Ọlọ́run ló ń pinnu bí ìgbésí ayé wa ṣe máa rí? [Jẹ́ kó fèsì.] Tó bá jẹ́ pé òun ni, á jẹ́ pé sísọ tó sọ pé káwọn ìránṣẹ́ òun yan ìyè kò nítumọ̀, kò sì mọ́gbọ́n dání nìyẹn.” Àpilẹ̀kọ tó wà lójú ìwé 10, nínú ìwé yìí á jẹ́ kó o mọ bó o ṣe lè yan ìyè.
Ilé Ìṣọ́ June 1
“Àwọn ìwé tó ń pèsè ìmọ̀ràn lórí ọmọ títọ́, ìfẹ́ àti béèyàn ṣe lè ṣàṣeyọrí wọ́pọ̀ lóde òní. Ṣé irú ìwé bẹ́ẹ̀ ti ràn ẹ́ lọ́wọ́ rí? [Jẹ́ kó fèsì.] Ọ̀pọ̀ ni ò ka ìmọ̀ràn tó ṣeé gbara lé tó wà nínú Bíbélì sí. [Ka 2 Tímótì 3:16.] Ìwé ìròyìn yìí sọ ìdí tá a fi lè gbẹ́kẹ̀ lé Bíbélì, ó sì fúnni ní àpẹẹrẹ àwọn ìmọ̀ràn tó wúlò tó wà nínú rẹ̀.”
Jí! April–June
“Ǹjẹ́ o ti ronú lórí ohun tó fà á tí ọ̀pọ̀ ìgbéyàwó fi ń tú ká, tó sì jẹ́ pé ìwọ̀nba díẹ̀ ló máa ń tọ́jọ́? [Jẹ́ kó fèsì.] Ẹsẹ Bíbélì yìí sọ ohun tó lè mú kí ìgbéyàwó tọ́jọ́. [Ka Hébérù 13:4.] Bíbélì kìlọ̀ pé àwọn tọkọtaya ò gbọ́dọ̀ dalẹ̀ ara wọn.” Fi àpilẹ̀kọ tó bẹ̀rẹ̀ lójú ìwé 14 hàn án.