Ohun Tó O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn
Ile Iṣọ May 1
“Báwọn àjálù tó ń ṣẹlẹ̀ lákòókò wa ṣe ń pọ̀ sí i ti mú káwọn kan máa ṣe kàyéfì pé bóyá ńṣe ni Ọlọ́run ń fìyà ẹ̀ṣẹ̀ wa jẹ wá. Kí lèrò ẹ? [Jẹ́ kó fèsì. Kó o wá ka 1 Jòhánù 4:8.] Àpilẹ̀kọ yìí ṣàlàyé ìdí tá ò fi lè dá Ọlọ́run lẹ́bi fáwọn ìrora tí àjálù ń fà.” Fi àpilẹ̀kọ tó wà lójú ìwé 30 hàn án.
Ile Iṣọ June 1
“Ọ̀kan lára àwọn ìtàn Bíbélì táwọn èèyàn mọ̀ dáadáa ni ìtàn nípa Nóà àti Ìkún Omi. Ǹjẹ́ o rò pé lóòótọ́ ni Ìkún Omi ṣẹlẹ̀? [Jẹ́ kó fèsì.] Ó dùn mọ́ni pé Jésù tọ́ka sí i pé ohun tó ṣẹlẹ̀ lóòótọ́ ni. [Ka Lúùkù 17:26, 27.] Ìwé ìròyìn yìí sọ àwọn ìdí tá a fi lè gbà pé Ìkún Omi ṣẹlẹ̀ lóòótọ́, ó sì ṣàlàyé àwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì tá a lè rí kọ́ látinú ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀hún.”
Jí! Apr.–June
“Ṣé o rò pé ìgbàgbọ́ nínú ohun asán léwu àbí nǹkan ṣeré ṣeré lásán ni? [Jẹ́ kó fèsì.] Gbọ́ ohun tí Bíbélì sọ. [Ka Aísáyà 65:11.] Àpilẹ̀kọ yìí sọ bóyá ìgbàgbọ́ nínú ohun asán bára mu pẹ̀lú ẹ̀kọ́ Bíbélì.” Fi àpilẹ̀kọ tó bẹ̀rẹ̀ lójú ìwé 12 hàn án.
“Ǹjẹ́ o rò pé àkókò tí ẹsẹ Bíbélì yìí sọ la wà yìí? [Ka 2 Tímótì 3:1-4, lẹ́yìn náà jẹ́ kó fèsì.] Ó yẹ ká fẹ́ láti mọ púpọ̀ sí i nípa ọjọ́ ìkẹyìn, torí àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lákòókò òpin yìí ń fi hàn pé ilẹ̀ ayé wa yìí ń bọ̀ wá dára. Ìwé ìròyìn yìí á túbọ̀ ṣàlàyé síwájú sí i.”