Ohun Tó O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn
Ilé Ìṣọ́ February 1
“Ǹjẹ́ o rò pé èèyàn lè mọ bí Ọlọ́run ṣe rí? [Jẹ́ kó fèsì.] Mo ní ohun kan tó o máa nífẹ̀ẹ́ sí lórí ìbéèrè yẹn.” Ka ohun tó wà lábẹ́ ìbéèrè 2 lójú ìwé 16 kẹ́ ẹ sì jíròrò rẹ̀, kó o sì ka ọ̀kan lára àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó wà níbẹ̀. Fún un ní ìwé ìròyìn náà, kó o sì ṣètò láti pa dà lọ jíròrò àwọn ìsọfúnni tó wà lábẹ́ ìbéèrè 3.
Ji! January–March
“Ǹjẹ́ o ti rò ó rí pé ṣé ó yẹ ká máa gbàdúrà sí àwọn ẹni mímọ́? [Jẹ́ kó fèsì. Kó o wá ka Jòhánù 14:6.] Ó ṣe kedere pé Ọlọ́run nìkan ló yẹ ká máa darí àwọn àdúrà wa sí, ká sì máa gbàdúrà lórúkọ Jésù.” Lo àpilẹ̀kọ tó bẹ̀rẹ̀ lójú ìwé 14.
Ilé Ìṣọ́ March 1
“Ọ̀pọ̀ èèyàn ló mọ iṣẹ́ ìwàásù mọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ǹjẹ́ o ti ṣe kàyéfì rí nípa ìdí tá a fi ń ṣe iṣẹ́ yìí? [Jẹ́ kó fèsì.] Gbọ́ ohun tí ẹsẹ Bíbélì yìí sọ. [Ka Mátíù 24:14.] Ìwé ìròyìn yìí dáhùn ìbéèrè bíi: Kí ni ìhìn rere náà? Kí ni Ìjọba náà? Kí sì ni òpin tó ń bọ̀?”
Ji! January–March
“Ó jọ pé àwọn tó ń nífẹ̀ẹ́ sí ìbẹ́yà-kan-náà-lòpọ̀ ti wá ń pọ̀ sí i báyìí. Kí tiẹ̀ ni Bíbélì sọ nípa ìbẹ́yà-kan-náà-lòpọ̀, ìyẹn kí ọkùnrin àti ọkùnrin tàbí obìnrin pẹ̀lú obìnrin máa bá ara wọn lò pọ̀? [Jẹ́ kó fèsì. Kó o wá ka Léfítíkù 18:22.] Bíbélì jẹ́ kó ṣe kedere pé àwọn tọkọtaya nìkan ni Ọlọ́run ṣètò ìbálòpọ̀ fún.” Lo àpilẹ̀kọ tó bẹ̀rẹ̀ lójú ìwé 22.