ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 1/13 ojú ìwé 4
  • Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tá A Lè Lò

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tá A Lè Lò
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2013
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tá A Lè Lò
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2014
  • Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tá A Lè Lò
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2012
  • Ohun Tó O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2011
  • Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tá A Lè Lò
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2011
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2013
km 1/13 ojú ìwé 4

Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tá A Lè Lò

Láti Bẹ̀rẹ̀ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ní Sátidé Àkọ́kọ́ Lóṣù February

“Ọ̀pọ̀ èèyàn ló máa ń sọ pé Èṣù ló wà nídìí gbogbo láabi tó ń ṣẹlẹ̀ láyé. Síbẹ̀, wọ́n máa ń béèrè pé: ‘Ibo ni Èṣù ti wá? Ṣé Ọlọ́run ló dá a?’ Kí lèrò tìẹ? [Jẹ́ kó fèsì.] Gbọ́ ohun tí ìwé yìí sọ.” Fi àpilẹ̀kọ tó wà ní ẹ̀yìn Ilé Ìṣọ́ February 1 han onílé, kẹ́ ẹ sì jọ jíròrò ìsọfúnni tó wà ní ìpínrọ̀ àkọ́kọ́ àti ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó wà níbẹ̀. Fún un ní ìwé ìròyìn náà, kó o sì ṣètò láti pa dà lọ jíròrò ìdáhùn sí ìbéèrè tó kàn.

Ilé Ìṣọ́ February 1

“Jọ̀wọ́, mo fẹ́ mọ ohun tó o rò nípa ọkùnrin kan tí gbogbo ẹlẹ́sìn Kristẹni àtàwọn Mùsùlùmí kà sí èèyàn pàtàkì. Mósè ni mo ní lọ́kàn. Kí ló máa ń wá sí ẹ lọ́kàn tó o bá gbọ́ orúkọ rẹ̀? [Jẹ́ kó fèsì.] Òótọ́ ni pé Mósè ṣe àwọn àṣìṣe kan, àmọ́ Bíbélì sọ nǹkan kan tó wúni lórí nípa irú ẹni tó jẹ́. [Ka Diutarónómì 34:10-12.] Ìwé ìròyìn yìí sọ mẹ́ta nínú àwọn ìwà rere tí Mósè ní àti bá a ṣe lè fara wé e.”

Jí! January–February

“Ọ̀pọ̀ èèyàn tó gbà pé àwọn olódodo máa jogún ìyè ni èrò wọn yàtọ̀ síra nípa ibi tí àwọn olódodo máa gbé títí láé. Kí ni ìwọ rò nípa ọ̀rọ̀ yìí? [Jẹ́ kó fèsì.] Bíbélì sọ fún wa pé ẹ̀bùn láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni ilẹ̀ ayé jẹ́ fún àwa èèyàn. [Ka Sáàmù 115:16.] Torí náà, ó bọ́gbọ́n mu, ó sì tún bá Ìwé Mímọ́ mu láti ronú pé a máa gbé títí láé nínú ayé tí Ọlọ́run ti tún ṣe. Àpilẹ̀kọ tó wà lójú ìwé 14 àti 15 nínú ìwé yìí dáhùn ìbéèrè pàtàkì méjì nípa Párádísè tí Ọlọ́run ṣèlérí pé ó máa wà lórí ilẹ̀ ayé.”

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́