Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tá A Lè Lò
Láti Bẹ̀rẹ̀ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ní Saturday Àkọ́kọ́ Lóṣù August
“Onírúurú ẹ̀sìn ni àwọn èèyàn ń ṣe, oríṣiríṣi ọ̀nà ni wọ́n sì ń gbà jọ́sìn Ọlọ́run. Ǹjẹ́ o mọ èrò Ọlọ́run nípa èyí? [Jẹ́ kó fèsì.] Wo ohun tí Jésù sọ nípa rẹ̀.” Mú Ilé Ìṣọ́ August 1 fún un, kẹ́ ẹ sì jọ ka àwọn ìsọfúnni tó wà lábẹ́ ìsọ̀rí àkọ́kọ́ lójú ìwé 16, kẹ́ ẹ jíròrò rẹ̀, kẹ́ ẹ sì ka ọ̀kan lára àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó wà níbẹ̀. Béèrè bóyá onílé á fẹ́ láti gba ìwé náà, kó o sì ṣètò láti pa dà lọ jíròrò ìdáhùn sí ìbéèrè tó kàn.
Ilé Ìṣọ́ August 1
“Ǹjẹ́ ó yẹ ká máa kọ́ àwọn ọmọ wa nípa Ọlọ́run nígbà tí wọ́n ṣì kéré, àbí ohun tó dára jù ni pé ká dúró dìgbà tí wọ́n bá dàgbà, ká sì gbà wọ́n láyè láti yan ẹ̀sìn tí wọ́n bá fẹ́? [Jẹ́ kó fèsì.] Gbọ́ ìtọ́ni tí Bíbélì fún àwọn bàbá. [Ka Éfésù 6:4.] Ìwé ìròyìn yìí sọ ohun tí àwọn òbí lè ṣe láti kọ́ àwọn ọmọ wọn nípa Ọlọ́run.”
Ji! July–September
“Ìpániláyà ti di ìṣòro tó kárí ayé. Kí lo rò pé ó ń fà á? [Jẹ́ kó fèsì.] Bíbélì sọ ọ̀rọ̀ kan tó fún wa ní ìrètí. [Ka Sáàmù 72:7, 14.] Ìwé ìròyìn yìí ṣàlàyé díẹ̀ lára àwọn ìdí tí ìpániláyà fi ń wáyé, ó sì jẹ́ ká mọ ohun tí Bíbélì sọ nípa bí ìpániláyà ṣe máa dópin àti ìgbà tó máa dópin.”