Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tá A Lè Lò
Láti Bẹ̀rẹ̀ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ní Saturday Àkọ́kọ́ Lóṣù August
“Lónìí, ojú tí àwọn èèyàn fi ń wo Jésù ní ẹgbẹ̀rún [2,000] ọdún méjì sẹ́yìn náà ni wọ́n sábà máa fi ń wò ó, bíi pé ó ṣì jẹ́ ìkókó tó wà ní ibùjẹ ẹran tàbí bí ọkùnrin kan tó ń kú lọ lórí òpó igi oró. Àmọ́ ipò wo lo rò pé Jésù wà báyìí? [Jẹ́ kó fèsì.] Wo ohun tí ìwé yìí sọ.” Fún onílé náà ní Ilé Ìṣọ́ August 1, kí ẹ sì jọ jíròrò ohun tó wà ní abẹ́ ìsọ̀rí àkọ́kọ́ lójú ìwé 16 àti ọ̀kan lára àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó wà níbẹ̀. Fún un ní ìwé ìròyìn náà, kí o sì ṣètò láti pa dà lọ jíròrò ìdáhùn sí ìbéèrè tó kàn.
Ilé Ìṣọ́ August 1
“Ọ̀pọ̀ èèyàn ló gbà pé iṣẹ́ ìyanu máa ń ṣẹlẹ̀. Ṣùgbọ́n àwọn míì ń ṣiyèméjì. Kí lèrò tìẹ, ṣe iṣẹ́ ìyanu máa ń ṣẹlẹ̀ lóòótọ́? [Jẹ́ kó fèsì.] Ìlérí nípa iṣẹ́ ìyanu tí Ọlọ́run máa ṣe lọ́jọ́ iwájú yìí ti jẹ́ kí ọ̀pọ̀ èèyàn nírètí. [Ka ọ̀kan lára àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó wà ní ojú ìwé 9 àti 10.] Ìwé ìròyìn yìí sọ ohun mẹ́ta táwọn èèyàn fi ń tako iṣẹ́ ìyanu.”
Ji! July–September
“Ǹjẹ́ o rò pé àwọn tó ti kú lè ran àwa tá a ṣì wà láàyè lọ́wọ́? [Jẹ́ kó fèsì.] Gbọ́ òótọ́ ọ̀rọ̀ tí Bíbélì sọ nípa ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sáwọn òkú. [Ka Oníwàásù 9:5] Bí àwọn ìbéèrè kan bá ń jà gùdù lọ́kàn rẹ tàbí tí ò ń ṣiyèméjì nípa ohun tó o lè ṣe, àpilẹ̀kọ yìí sọ ìdí tó fi máa dáa pé kó o yẹ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wò, kó o sì ṣe ohun tó bá sọ gan-an.” Fi àpilẹ̀kọ tó bẹ̀rẹ̀ lójú ìwé 10 hàn án.