Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tá A Lè Lò
Láti Bẹ̀rẹ̀ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ní Saturday Àkọ́kọ́ Lóṣù May
“Lójú tìẹ ṣé ìsìn ń mú kí àwọn èèyàn fìfẹ́ hàn kí wọ́n sì máa gbé ní àlàáfíà àbí ńṣe ló ń fa ìkórìíra àti ìwà ipá? [Jẹ́ kó fèsì.] Jẹ́ kí n fi ohùn kan tí wàá nífẹ̀ẹ́ sí nípa ọ̀rọ̀ yìí hàn ẹ́.” Fún onílé ní ẹ̀dà Ilé Ìṣọ́ May 1, kẹ́ ẹ wá jọ ka àwọn ìsọfúnni tó wà lábẹ́ ìsọ̀rí àkọ́kọ́ lójú ìwé 16 àti ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan tí wọ́n tọ́ka sí. Fún un ní ìwé ìròyìn náà, kó o sì ṣètò láti pa dà lọ jíròrò ìdáhùn sí ìbéèrè tó kàn.
May 1
“Ọ̀pọ̀ ló gbà pé ó dára gan-an kí ìsìn máa lọ́wọ́ nínú ìṣèlú, nígbà tí àwọn míì rò pé kò sí ohun tó yẹ kí ó da ìsìn àti ìṣèlú pọ̀. Kí lèrò ẹ? [Jẹ kó fèsì.] Kíyè sí ohun tí Jésù ṣe nígbà tí àwọn èèyàn fẹ́ kí ó lọ́wọ́ nínú ìṣèlú táwọn èèyàn ń ṣe nígbà ayé rẹ̀. [Ka Jòhánù 6:15.] Ìwé ìròyìn yìí ṣàlàyé ìdí tí Jésù fi hùwà lọ́nà bẹ́ẹ̀, ó sì tún ṣàlàyé ọ̀nà tó dára jù tí àwọn Kristẹni lè gbà rán ìlú lọ́wọ́.”
April–June
Fi àpilẹ̀kọ tó wà lójú ìwé 12 hàn án, kó o wá sọ pé: “Ó dà bí ẹni pé ọ̀pọ̀ èèyàn ni kò mọ ọ̀nà tó tọ́ láti gbàdúrà. Kí ni ìwọ ti kíyè sí? [Jẹ́ kó fèsì.] Jésù to àwọn nǹkan tó ṣe pàtàkì tó yẹ ká gbàdúrà nípa rẹ̀. [Ka Mátíù 6:9-13.] Àpilẹ̀kọ yìí ṣàlàyé àwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì tó wà nínú àdúrà àwòṣe náà. Àpilẹ̀kọ yìí máa jẹ́ kó o mọ bó o ṣe lè gbàdúrà lọ́nà tó túbọ̀ nítumọ̀, àti lọ́nà tí Ọlọ́run á fi gbọ́ àdúrà rẹ.”