Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tá A Lè Lo
Láti Bẹ̀rẹ̀ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ní Saturday Àkọ́kọ́ Lóṣù June
Ka Sáàmù 83:18, kó o wá sọ pé: “Ẹsẹ Bíbélì tá a kà yìí fi hàn pé Ọlọ́run ní orúkọ. Ǹjẹ́ o rò pé ó ṣe pàtàkì pé ká máa lo orúkọ Ọlọ́run? [Jẹ́ kó fèsì.] Kíyè sí ohun tí ibí yìí sọ.” Fún onílé ní ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ June 1, kẹ́ ẹ sì jọ jíròrò àwọn ìsọfúnni tó wà lábẹ́ ìsọ̀rí àkọ́kọ́ lójú ìwé 16. Fún un ní ìwé ìròyìn náà, kó o sì ṣètò láti pa dà lọ jíròrò ìdáhùn sí ìbéèrè tó kàn.
June 1
“Mo fẹ́ mọ èrò rẹ nípa kókó pàtàkì yìí. [Ṣí ìwé ìròyìn náà sí ojú ìwé 3, kó o sì tọ́ka sí àwọn gbólóhùn tá a tò síbẹ̀.] Èwo nínú àwọn gbólóhùn yìí lo gbà pé ó jẹ́ òótọ́ nípa Bíbélì? [Jẹ́ kó fèsì.] Wo ohun tí Bíbélì fúnra rẹ̀ sọ pé òun lè ṣe. [Ka Róòmù 15:4.] Ìwé ìròyìn yìí jíròrò àwọn nǹkan márùn-ún tó mú kí Bíbélì yàtọ̀ sí àwọn ìwé yòókù, ó sì sọ bí Bíbélì ṣe lè ṣe wá láǹfààní.”
April–June
“Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń sọ pé béèyàn kò bá parọ́, kò le ṣe àṣeyọrí tó tọ́jọ́. Kí lèrò rẹ? [Jẹ́ kó fèsì.] Wo ọ̀rọ̀ tó ń múni ronú jinlẹ̀ yìí ná. [Ka Lúùkù 12:15.] Ìwé ìròyìn yìí ṣàlàyé ìdí tó fi bọ́gbọ́n mu pé kéèyàn jẹ́ olóòótọ́.”