Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní June 11
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ JUNE 11
Orin 123 àti Àdúrà
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
bt orí 22 ìpínrọ̀ 1 sí 6 (25 min.)
□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Ìdárò 1-2 (10 min.)
No. 1: Ìdárò 2:11-19 (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Àwọn Ọ̀nà Wo Ni Àwọn Èèyàn Ń Gbà “Run Ilẹ̀ Ayé”?—Ìṣí. 11:18 (5 min.)
No. 3: Ojúṣe Òbí sí Ọmọ—td 19D (5 min.)
□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
5 min: Àwọn Ìfilọ̀.
10 min: Àwọn Àṣeyọrí Wo La Ṣe? Ìjíròrò. Akọ̀wé ni kó ṣe apá yìí. Sọ àwọn àṣeyọrí tẹ́ ẹ ṣe lásìkò Ìrántí Ikú Kristi, kó o sì gbóríyìn fún ìjọ fún ìgbòkègbodò wọn. Ní kí àwọn ará sọ àwọn ìrírí tí wọ́n ní nígbà tí wọ́n pín ìwé ìkésíni sí Ìrántí Ikú Kristi, nígbà tí wọ́n pa dà lọ ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn ẹni tuntun tó wá sí Ìrántí Ikú Kristi àti nígbà tí wọ́n ṣe aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́.
20 min: “Ìdí Méjìlá Tá A Fi Ń Wàásù.” Ìjíròrò.
Orin 47 àti Àdúrà