Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tá A Lè Lò
Láti Bẹ̀rẹ̀ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ní Sátidé Àkọ́kọ́ Lóṣù June
“Gbogbo èèyàn ló ń sọ pé àwọn fẹ́ kí àlàáfíà jọba láyé yìí. Àmọ́ àwọn èèyàn ṣì ń jagun. Kí ni ìwọ rò pé ó fà á tí àlàáfíà kò fi sí láyé?” Jẹ́ kó fèsì. Lẹ́yìn náà, fi ẹ̀yìn Ilé Ìṣọ́ June 1 hàn án, kẹ́ ẹ sì jọ jíròrò ohun tó wà lábẹ́ ìbéèrè àkọ́kọ́ àti ẹsẹ Bíbélì kan ó kéré tán. Fún un ní ìwé ìròyìn náà, kó o sì ṣètò láti pa dà lọ jíròrò ìbéèrè tó kàn.
Àkíyèsí: Kí ẹ ṣe àṣefihàn ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ yìí nígbà ìpàdé fún iṣẹ́ ìsìn pápá tẹ́ ẹ máa ṣe ní June 1.
Ilé Ìṣọ́ June 1
“À ń lọ sọ́dọ̀ àwọn èèyàn láti bá wọn sọ̀rọ̀ nípa ìṣòro kan tó ń jà ràyìn. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ gbogbo èèyàn ni àwọn kan ti ṣe ẹ̀tanú sí lọ́nà kan tàbí òmíràn. Ǹjẹ́ o rò pé ibì kankan wà láyé yìí tí àwọn èèyàn kì í ti í ṣe ẹ̀tanú sí ara wọn? [Jẹ́ kó fèsì.] Jẹ́ ká wo ojú tí Ọlọ́run fi ń wo gbogbo èèyàn. [Ka Ìṣe 10:34.] Ìwé yìí sọ bí Ọlọ́run ṣe máa mú ẹ̀tanú kúrò pátápátá.”
Jí! May–June
“Wàá gbà pẹ̀lú mi pé kò rọrùn láti tọ́ ọmọ ní àkókò tá a wà yìí. Àbí? [Jẹ́ kó fèsì.] Àmọ́ ìmọ̀ràn látinú Bíbélì ti ran ọ̀pọ̀ àwọn òbí lọ́wọ́. Bí àpẹẹrẹ, ẹsẹ Bíbélì yìí jẹ́ ká mọ̀ pé ó yẹ kí àwọn bàbá máa gbóríyìn fún àwọn ọmọ wọn, kí wọ́n lè máa dá ìpinnu ṣe fúnra wọn. [Ka Kólósè 3:21.] Àpilẹ̀kọ yìí sọ ohun márùn-ún tó máa ran àwọn bàbá lọ́wọ́.”