Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tá A Lè Lò
Láti Bẹ̀rẹ̀ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ní Sátidé Àkọ́kọ́ Lóṣù June
“À ń bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ ní ṣókí nípa ìbéèrè pàtàkì yìí. [Fi ìbéèrè àkọ́kọ́ tó wà lẹ́yìn Ilé Ìṣọ́ June 1 hàn án.] Kí lèrò rẹ?” Jẹ́ kó fèsì. Ẹ jọ jíròrò àlàyé tó wà lábẹ́ ìbéèrè náà àti ọ̀kan lára àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó wà níbẹ̀, ó kéré tán. Fún un ní ìwé ìròyìn náà, kó o sì ṣètò láti pa dà wá jíròrò ìdáhùn sí ìbéèrè tó kàn.
Ilé Ìṣọ́ June 1
“Ó tó nǹkan bí mílíọ̀nù mẹ́fà èèyàn tó ń kú lọ́dọọdún nítorí wọ́n ń mu sìgá. Ṣé o rò pé nǹkan kan wà tá a lè ṣe láti dín ìṣòro tó gbalẹ̀ kan yìí kù? [Jẹ́ kó fèsì.] Torí ọ̀pọ̀ ti wá mọ ojú tí Ọlọ́run fi ń wo mímu sìgá, wọ́n ti jáwọ́ nínú àṣà yìí tàbí tí wọn ò fẹnu kàn án rárá. Bí àpẹẹrẹ, ẹsẹ Bíbélì yìí tí mú kí àwọn kan ronú nípa ìpalára tí sìgá máa ń fà fún àwọn ẹlòmíì. [Ka 1 Kọ́ríńtì 10:24.] Ìwé ìròyìn yìí ṣàlàyè pé téèyàn bá mọ ojú tí Ọlọ́run fi ń wo mímu sìgá, ó máa ràn án lọ́wọ́ kó lè jáwọ́ níbẹ̀.”
Ji! May–June
“Ìdí tá a fi wá síbi ni pé à ń jẹ́ káwọn èèyàn mọ bí wọ́n ṣe lè bójú tó ìṣòro kan tó ti wá ń wọ́pọ̀ nínú ìdílé báyìí. Ńṣe ló túbọ̀ ń nira gan-an fáwọn ọ̀dọ́ láti gba ìbáwí táwọn òbí wọn bá fún wọn. Tírú ẹ̀ bá wáyé nínú ìdílé kan, ṣé kì í ṣe pé àwọn tí wọ́n ń fún ní ìbáwí ti ro ara wọn pin pé àwọn ò wúlò fún nǹkan kan? [Jẹ́ kó fèsì.] Wo ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan tó jẹ́ ká mọ̀ pé kò yẹ kéèyàn máa kọ ìbáwí. [Ka Òwe 3:12.] Ìwé ìròyìn yìí jẹ́ ká mọ ìdí tó fi máa ṣe ẹni tí wọ́n ń fún ní ìbáwí láǹfààní tó bá ń ronú lórí ohun tó mú kí wọ́n fún òun ní ìbáwí dípò kó kàn máa ronú lórí ìbáwí tí wọ́n fún un.”