Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tá A Lè Lò
Láti Bẹ̀rẹ̀ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ní Sátidé Àkọ́kọ́ Lóṣù May
“À ń lọ sọ́dọ̀ àwọn èèyàn ká lè bá wọn sọ̀rọ̀ ní ṣókí nípa ìbéèrè pàtàkì kan. [Fi ìbéèrè àkọ́kọ́ tó wà lẹ́yìn Ilé Ìṣọ́ May 1 hàn án.] Kí lèrò rẹ?” Jẹ́ kó fèsì. Ẹ jọ jíròrò àlàyé tó wà lábẹ́ ìbéèrè náà àti ọ̀kan lára àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó wà níbẹ̀, ó kéré tán. Fún un ní ìwé ìròyìn náà, kó o sì ṣètò láti pa dà wá jíròrò ìdáhùn sí ìbéèrè tó kàn.
Ilé Ìṣọ́ May 1
“A wá sọ́dọ̀ ẹ nítorí a rí i pé ọ̀pọ̀ èèyàn ló fẹ́ mọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú. Tó o bá ronú nípa ọjọ́ ọ̀la, báwo ló ṣe máa ń rí lára rẹ? Ṣé ọkàn rẹ máa ń balẹ̀ ni, àbí ẹ̀rù máa ń bà ẹ́? [Jẹ́ kó fèsì. Lẹ́yìn náà, ka ọ̀kan lára àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó wà nínú àpótí náà, “Àwọn Ohun Tí Ọlọ́run Sọ Nípa Ọjọ́ Ọ̀la.”] Ìwé ìròyìn yìí sọ díẹ̀ lára àwọn nǹkan tí Ọlọ́run sọ pé ó máa ṣẹlẹ̀, ó sì ṣàlàyé ìdí tó fi dá wa lójú pé àwọn ìlérí Ọlọ́run máa ṣẹ.”
Ji! May–June
“A fẹ́ sọ ohun tẹ́ ẹ lè ṣe sí ìṣòro kan tó ti wá wọ́pọ̀ gan-an báyìí. Àwọn ìṣòro ti mú kí ayé sú àwọn ẹlòmíì débi pé wọ́n ti ronú láti pa ara wọn. Ṣó o rò pé àwọn tí ìṣòro wọ́n ti le débi tí wọ́n fi ń ronú àtipa ara wọn yìí fẹ́ kú lóòótọ́, àbí ńṣe ni wọ́n kàn ń wá ojútùú sí ìṣòro wọn? [Jẹ́ kó fèsì.] Ìlérí Bíbélì yìí tí mú kí ọ̀pọ̀ èèyàn gbà pé ọ̀la ṣì ń bọ̀ wá dára. [Ka Ìṣípayá 21:3, 4.] Ìwé ìròyìn yìí sọ ìdí pàtàkì mẹ́ta tó fi yẹ kí èèyàn máa wà láàyè láìka àwọn ìṣòro tó ní sí.”