Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tá A Lè Lò
Láti Bẹ̀rẹ̀ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ní Sátidé Àkọ́kọ́ Lóṣù October
“À ń ṣe ìbẹ̀wò ráńpẹ́ sọ́dọ̀ àwọn aládùúgbò wa lónìí. Púpọ̀ lára àwọn tá a bá sọ̀rọ̀ ló sọ pé ọ̀kan lára ìṣòro tó kà wọ́n láyà jù lọ ni ikú èèyàn wọn kan. Ṣé bó ṣe rí lára ìwọ náà nìyẹn? [Jẹ́ kó fèsì.] Mo rí i pé ohun tó wà nínú ìwé yìí ń tuni nínú gan-an.” Fi ẹ̀yìn Ilé Ìṣọ́ October 1 hàn án, kí ẹ sì jọ jíròrò àlàyé tó wà lábẹ́ ìbéèrè àkọ́kọ́ àti ó kéré tán, ọ̀kan lára àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó wà níbẹ̀. Fún un ní ìwé ìròyìn náà, kí o sì ṣètò láti pa dà wá kí ẹ lè jọ jíròrò ìbéèrè tó tẹ̀ lé e.
Ilé Ìṣọ́ October 1
“À ń ṣèbẹ̀wò ráńpẹ́ láti fún àwọn èèyàn níṣìírí pé kí wọ́n máa ka Bíbélì. A mọ̀ pé àwọn èèyàn kan nífẹ̀ẹ́ sí Bíbélì, àmọ́ àwọn míì ò kà á sí. Ìwọ ńkọ́? [Jẹ́ kó fèsì.] Gbọ́ ohun tí Bíbélì sọ níbí yìí. [Ka 1 Tẹsalóníkà 2:13.] Mo mọ̀ pé ìwọ náà máa gbà pé tó bá jẹ́ ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni Bíbélì ti wá lóòótọ́, ó yẹ ká máa kà á. Ìwé ìròyìn yìí sọ ohun tó wà nínú Bíbélì àti ìdí tó fi yẹ ká nífẹ̀ẹ́ rẹ̀.”
Ji! September–October
“Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń ṣàníyàn nípa ohun kan tó ti ń di ìṣòro ńlá báyìí, ìyẹn ni mímu ọtí líle ní àmujù. Ǹjẹ́ ìwọ náà ti kíyè sí i? [Jẹ́ kó fèsì. Lẹ́yìn náà ka Oníwàásù 9:7.] Lóòótọ́, Bíbélì dẹ́bi fún mímu ọtí yó tàbí mímu ọtí àmujù, àmọ́ kò ka mímu ọtí líle níwọ̀nba léèwọ̀. Ìwé ìròyìn Jí! yìí dáhùn ìbéèrè pàtàkì mẹ́ta nípa ọtí líle, ó sì sọ àwọn ìlànà Bíbélì tó ṣeé fọkàn tán tó sì gbéṣẹ́ táá jẹ́ ká mọ irú ojú tó yẹ ká fi máa wo ọtí líle.” Fi àpilẹ̀kọ tó wà lójú ìwé 14 hàn án.