Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tá A Lè Lò
Láti Bẹ̀rẹ̀ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ní Saturday Àkọ́kọ́ Lóṣù October
“Ní àkókò líle koko yìí, gbogbo wa là ń dojú kọ àwọn ìṣòro tí kì í jẹ́ kí nǹkan rọgbọ fún ìdílé. Ibo lo ronú pé a ti lè rí ìtọ́sọ́nà tó ṣe é gbára lé, èyí tó máa jẹ́ kí ìdílé wa láyọ̀?” Jẹ́ kó fèsì. Mú Ilé Ìṣọ́ October 1 fún un, kẹ́ ẹ sì jọ ka àwọn ìsọfúnni tó wà lábẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìsọ̀rí tó wà lójú ìwé 16 àti 17, kẹ́ ẹ sì jíròrò rẹ̀. Ó kéré tán, kẹ́ ẹ ka ọ̀kan lára àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó wà níbẹ̀. Béèrè bóyá ó máa fẹ́ láti gba ìwé náà, kó o sì ṣètò láti pa dà lọ jíròrò ìdáhùn sí ìbéèrè tó kàn.
Ilé Ìṣọ́ October 1
Fi iwájú ìwé ìròyìn náà hàn án, kó o sì béèrè pé: “Báwo ló ṣe máa rí lára rẹ tó o bá mọ̀ pé kì í ṣe òótọ́ ni ohun tí wọ́n kọ́ ẹ nípa Ọlọ́run? [Jẹ́ kó fèsì.] Gbọ́ ohun tí Jésù sọ nípa bá a ṣe lè dá òótọ́ mọ̀ yàtọ̀ sí irọ́. [Ka Jòhánù 17:17.] Bíbélì nìkan ló sọ òótọ́ fún wa nípa Ọlọ́run. Ìwé ìròyìn yìí jíròrò ohun márùn-ún tí kì í ṣe òótọ́ táwọn èèyàn sábà máa ń sọ nípa Ọlọ́run, èyí tí Bíbélì tú àṣírí rẹ̀.”
Ji! October–December
“Iṣẹ́ kan tó kan gbogbo ìdílé ni à ń jẹ́ ládùúgbò yín lónìí. Kí lẹ rò pé ó jẹ́ olórí ìṣòro tí àwọn òbí máa ń ní lóde òní bí wọ́n ṣe ń tọ́ àwọn ọmọ wọn? [Jẹ́ kó fèsì.] Ọ̀pọ̀ òbí ló máa ń fẹ́ gba ìmọ̀ràn látinú Bíbélì. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀rọ̀ ọgbọ́n tó wà nínú ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí máa ran àwọn òbí lọ́wọ́ tí wọ́n bá ń bá àwọn ọmọ wọn wí. [Ka Éfésù 4:31.] Ìwé ìròyìn yìí sọ bí ìmọ̀ràn Bíbélì ṣe lè ran àwọn òbí lọ́wọ́ kí wọ́n lè tọ́ àwọn ọmọ wọn yanjú, láti ìgbà ìkókó títí ọmọ náà á fi bàlágà.”