Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ October 10
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ OCTOBER 10
Orin 44 àti Àdúrà
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
bt orí 11 ìpínrọ̀ 1 sí 4, àti àpótí tó wà lójú ìwé 84, 86 àti 87 (25 min.)
Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Òwe 7-11 (10 min.)
No. 1: Òwe 8:1-21 (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Ǹjẹ́ O Lè Dá Àwọn Wòlíì Èké Mọ̀?—td 44A (5 min.)
No. 3: Ìdí Tí Ìwé Mímọ́ Fi Kìlọ̀ Lòdì sí Dídi “Olódodo Àṣelékè”—Oníw. 7:16 (5 min.)
Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
5 min: Àwọn Ìfilọ̀. Jíròrò “Àwọn Kókó Inú Ìròyìn Iṣẹ́ Ìsìn” tó wà lójú ìwé 8. Gbóríyìn fún àwọn ará nítorí ipa tí wọ́n kó láti mú kí ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wa ti oṣù April dára gan-an.
15 min: Ǹjẹ́ O Ti Gbìyànjú Ẹ̀ Wò? Ìjíròrò. Ní ṣókí, sọ àsọyé kan tó dá lórí àwọn àbá tó jáde nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa lẹ́nu àìpẹ́ yìí, ìyẹn àwọn àbá tó wà nínú àwọn àpilẹ̀kọ tí àkòrí rẹ̀ sọ pé: “Ṣé O Lè Máa Kópa Nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Láwọn Ọjọ́ Sunday?” (km 5/11) àti “Ìjẹ́rìí Òpópónà Tó Gbéṣẹ́” (km 6/11). Ní kí àwọn ará sọ bí wọ́n ṣe fi àwọn àbá tó wà nínú àwọn àpilẹ̀kọ náà sílò àti àwọn àǹfààní tí wọ́n ti rí.
15 min: “Ran Àwọn Èèyàn Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lè Ronú Jinlẹ̀.” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Lẹ́yìn tó o bá ti jíròrò ìpínrọ̀ 3, ṣe àṣefihàn kan, kí akéde kan fi ọ̀rọ̀ gún ẹni tó ń bá sọ̀rọ̀ lára bó ṣe ń dáhùn ìbéèrè táwọn èèyàn sábà máa ń béèrè ní ìpínlẹ̀ ìwàásù yín tàbí ọ̀rọ̀ tó lè bẹ́gi dínà ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀. Lẹ́yìn náà, kó o wá ṣe àṣefihàn míì, àmọ́ lọ́tẹ̀ yìí kí akéde náà fèrò wérò pẹ̀lú onílé lórí ìbéèrè kan náà.
Orin 102 àti Àdúrà