ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 9/14 ojú ìwé 4
  • Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tá A Lè Lò

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tá A Lè Lò
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2014
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tá A Lè Lò
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2013
  • Sample Presentations
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2011
  • Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tá A Lè Lò
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2012
  • Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tá A Lè Lò
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2014
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2014
km 9/14 ojú ìwé 4

Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tá A Lè Lò

Láti Bẹ̀rẹ̀ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní Sátidé Àkọ́kọ́ Lóṣù October

“À ń lọ sọ́dọ̀ àwọn èèyàn ká lè bá wọn sọ̀rọ̀ ní ṣókí nípa ìjọba rere. Ǹjẹ́ o rò pé ìjọba kankan lè fòpin sí àwọn ìṣòro bí ìwà ipá àti ìwà ìrẹ́jẹ?” Jẹ́ kó fèsì. Rán onílé létí ohun tí Jésù kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ nínú Àdúrà Olúwa pé kí wọ́n máa gbàdúrà kí ìjọba rere kan dé, ìyẹn Ìjọba Ọlọ́run. Fi ẹ̀yìn Ilé Ìṣọ́ October 1 han onílé, kẹ́ ẹ sì jọ jíròrò àlàyé tó wà lábẹ́ ìbéèrè àkọ́kọ́ àti ó kéré tán, ọ̀kan lára àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó wà níbẹ̀. Fún un ní ìwé ìròyìn náà, kó o sì ṣètò láti pa dà lọ jíròrò ìdáhùn sí ìbéèrè tó kàn.

Ilé Ìṣọ́ October 1

“À ń bá àwọn aládùúgbò wa sọ̀rọ̀ ní ṣókí nípa àdúrà kan tá a mọ̀ dáadáa tí Jésù kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀. [Ka Mátíù 6:9, 10.] Ǹjẹ́ ẹ tiẹ̀ mọ ohun tí Ìjọba náà jẹ́ gan-an àti ìdí tí Jésù fi tẹnu mọ́ ọn nínú ẹ̀kọ́ rẹ̀? [Jẹ́ kó fèsì.] Ìwé ìròyìn yìí sọ ohun tí Bíbélì fi kọ́ni nípa Ìjọba Ọlọ́run àti àwọn nǹkan àgbàyanu tí Ìjọba Ọlọ́run yóò ṣe fún aráyé.”

Ji! September–October

“À ń bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ nípa ìbéèrè pàtàkì yìí. [Fi àkòrí iwájú ìwé ìròyìn hàn-án.] Kí ló lè mú ká jẹ́ èèyàn àlàáfíà? [Jẹ́ kó fèsì.] Oríṣiríṣi nǹkan ló lè dá aáwọ̀ sílẹ̀. Síbẹ̀, kì í ṣe gbogbo èèyàn ló máa gbà pẹ̀lú rẹ pé kí àwọn parí aáwọ̀ náà. Ìdí nìyẹn tí Bíbélì fi gbà wá nímọ̀ràn yìí. [Ka Róòmù 12:18.] Ìwé ìròyìn yìí sọ àwọn ìlànà Bíbélì márùn-ún tó lè jẹ́ ká jẹ́ èèyàn àlàáfíà.” Fi àpótí tó wà lójú ìwé 6 hàn án.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́