Àwọn Ìfilọ̀
◼ Ìwé tá a máa lò ní September àti October: Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! November àti December: Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? tàbí Ṣé Wàá Fẹ́ Mọ Òtítọ́?
◼ Ọ̀sẹ̀ April 6 la máa sọ àkànṣe àsọyé fún gbogbo èèyàn ní àkókò Ìrántí Ikú Kristi ti ọdún 2015. A máa ṣe ìfilọ̀ àkòrí àsọyé náà tó bá yá. Kí àwọn ìjọ tó bá ní ìbẹ̀wò alábòójútó àyíká tàbí àpéjọ àyíká ní òpin ọ̀sẹ̀ yẹn sọ àkànṣe àsọyé wọn ní ọ̀sẹ̀ tó bá tẹ̀ lé e. Kí ìjọ kankan má ṣe sọ àsọyé yìí ṣáájú April 6.
◼ Bẹ̀rẹ̀ láti oṣù September, àkòrí àsọyé fún gbogbo ènìyàn tí àwọn alábòójútó àyíká yóò máa sọ ni, “Bí Ọgbọ́n Ọlọ́run Ṣe Ń Ṣe Wá Láǹfààní.”