Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ October 6
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ OCTOBER 6
Orin 18 àti Àdúrà
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
cl orí 14 ìpínrọ̀ 1 sí 9 (30 min.)
Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Diutarónómì 1-3 (10 min.)
No. 1: Diutarónómì 2:16-30 (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Àwọn Kristẹni Gbọ́dọ̀ Bọ̀wọ̀ fún Ìlànà Ipò Orí—td 19B (5 min.)
No. 3: Ojúṣe Àwọn Kristẹni Òbí Sí Àwọn Ọmọ—td 19D (5 min.)
Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
10 min: Fi Àwọn Ìwé Ìròyìn Lọni ní Oṣù October. Ìjíròrò. Kọ́kọ́ fi àwọn ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tó wà lójú ìwé yìí ṣe àṣefihàn bí a ṣe lè fi àwọn ìwé ìròyìn náà lọni. Lẹ́yìn náà, ẹ jíròrò àwọn ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ náà láti ìbẹ̀rẹ̀ dópin.
10 min: Ohun tó ń fẹ́ àbójútó nínú ìjọ.
10 min: Báwo La Ṣe Ṣe Sí? Ìjíròrò. Ní kí àwọn ará sọ bí wọ́n ṣe jàǹfààní nígbà tí wọ́n lo àwọn àbá tó wà nínú àpilẹ̀kọ náà, “Mú Kí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Sunwọ̀n Sí I—Múra Ọkàn Onílé Sílẹ̀ De Ìgbà Ìpadàbẹ̀wò.” Ní kí wọ́n sọ àwọn ìrírí tó gbádùn mọ́ni tí wọ́n ní.
Orin 83 àti Àdúrà