Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ September 29
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ SEPTEMBER 29
Orin 69 àti Àdúrà
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
cl orí 13 ìpínrọ̀ 19 sí 23, àpótí tó wà lójú ìwé 137 (30 min.)
Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Númérì 33-36 (10 min.)
No. 1: Númérì 33:24-49 (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: A Lè Jí Dìde Kúrò Nínú Ikú!—lr orí 35 (5 min.)
No. 3: Ìdè Ìgbéyàwó Gbọ́dọ̀ Ní Ọlá—td 19A (5 min.)
Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
10 min: Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní Sátidé Àkọ́kọ́. Ìjíròrò. Lo ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tó wà lójú ìwé 4 láti ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní Sátidé àkọ́kọ́ lóṣù October. Gba àwọn ará níyànjú pé kí wọ́n jáde òde ẹ̀rí lọ́jọ́ yẹn.
10 min: Kí La Rí Kọ́? Ìjíròrò. Ẹ ka Ìṣe 4:13 àti 2 Kọ́ríńtì 4:1, 7. Ẹ jíròrò bí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa.
10 min: Fọ̀rọ̀ Wá Ọ̀rọ̀ Wò Lẹ́nu Olùṣekòkáárí Ìgbìmọ̀ Àwọn Alàgbà. Kí ni ojúṣe yín gẹ́gẹ́ bí olùṣekòkáárí ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà ní nínú? Àwọn nǹkan wo lẹ máa ń gbé yẹ̀ wò kí ẹ tó yan iṣẹ́ fún àwọn arákùnrin ní Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn? Kí nìdí tí kò fi yẹ ká máa wo olùṣekòkáárí ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà bí olórí àwọn alàgbà tàbí olórí ìjọ?
Orin 4 àti Àdúrà