Orin 4
Bá A Ṣe Lè Ní Orúkọ Rere Lọ́dọ̀ Ọlọ́run
Bíi Ti Orí Ìwé
1. Títí ayé wa, Ojoojúmọ́ la ńfẹ́
Máa lóókọ rere Ní ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.
Táa bá ńṣohun tó tọ́ Ní ojú Jèhófà,
Aó mú ọkàn rẹ̀ Kún fún ayọ̀.
2. Wíwá orúkọ, Ògo òun òkìkí,
Pẹ̀lú ojúure, Látọ̀dọ̀ ayé yìí
Asán ni gbogbo rẹ̀. Báa bá dọ̀rẹ́ ayé,
Aò ní rójúure Ti Jèhófà.
3. Àwa fẹ́ kí Jáà Kọrúkọ wa sínú
Ìwé títí láé Kó sì máa rántí rẹ̀.
Òun la lè gbára lé, Ká dúró lé òótọ́
Ká lóókọ rere Títí láéláé.
(Tún wo Jẹ́n. 11:4; Òwe 22:1; Mál. 3:16; Ìṣí. 20:15.)