Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tá A Lè Lò
Láti Bẹ̀rẹ̀ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ní Sátidé Àkọ́kọ́ Lóṣù October
“Mo mọ̀ pé wàá gbà pẹ̀lú mi pé ẹ̀mí àwa èèyàn kì í gùn bíi ti tẹ́lẹ̀ mọ́. Ǹjẹ́ o rò pé ìgbà kan ń bọ̀ tí àìsàn kò ní sí mọ́, tí àwa èèyàn á sì máa pẹ́ láyé dáadáa? [Jẹ́ kó fèsì.] Gbọ́ ohun tí ìwé yìí sọ.” Fún onílé ní Ilé Ìṣọ́ October 1, kẹ́ ẹ sì jọ jíròrò ìsọfúnni tó wà lábẹ́ ìsọ̀rí àkọ́kọ́ ní ojú ìwé 16 àti ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tá a tọ́ka sí níbẹ̀. Fún un ní ìwé ìròyìn náà, kó o sì ṣètò láti pa dà lọ jíròrò ìdáhùn sí ìbéèrè tó kàn.
Ilé October 1
“Ìdí tá a fi wá sọ́dọ̀ rẹ ni pé ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń kọminú sí bí ìwà ìbàjẹ́ ṣe túbọ̀ ń gbilẹ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ajé àti láàárín àwọn tó ń ṣèjọba. Ǹjẹ́ o rò pé nǹkan kan tiẹ̀ wà tá a lè ṣe sí ìṣòro yìí? [Jẹ́ kó fèsì.] Gbọ́ ohun tí Bíbélì sọ pé Jésù máa ṣe fáwọn tí wọ́n ti hùwà ìbàjẹ́ sí. [Ka Sáàmù 72:12-14.] Ìwé ìròyìn yìí sọ bí ìwà ìbàjẹ́ ṣe máa dópin láìpẹ́.”
Ji! October–December
“Ká sọ pé o lágbára láti yí nǹkan kan pa dà tó máa mú kí ayé yìí dáa, kí ni wàá fẹ́ yí pa dà? [Jẹ́ kó fèsì.] Ohun tí Bíbélì sọ jẹ́ ká mọ ìdí tí àwọn èèyàn kò fi lè tún ayé yìí ṣe. [Ka Jeremáyà 10:23.] Ìwé ìròyìn yìí ṣàlàyé ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ṣe láti mú kí ayé yìí dáa.”