ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 9/11 ojú ìwé 4
  • Àwọn Ìfilọ̀

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Ìfilọ̀
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2011
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2011
km 9/11 ojú ìwé 4

Àwọn Ìfilọ̀

◼ Ìwé tá a máa lò ní September: Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Ẹ sapá láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nígbà àkọ́kọ́ tẹ́ ẹ bá fún àwọn èèyàn ní ìwé náà. Bí onílé bá ti ní ìwé náà, tí kò sì fẹ́ kí á wá máa kọ́ òun lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ẹ lè fún un ní àwọn ìwé ìròyìn tí ọjọ́ wọn ti pẹ́ tàbí ìwé pẹlẹbẹ èyíkéyìí tó sọ̀rọ̀ nípa ohun tó nífẹ̀ẹ́ sí. October: Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! Ẹ fún ẹni tó bá nífẹ̀ẹ́ sọ́rọ̀ wa ní ìwé àṣàrò kúkúrú náà Ṣé Wàá Fẹ́ Mọ Òtítọ́?, kẹ́ ẹ sì sapá láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. November: Kí Ló Wà Nínú Bíbélì? Láfikún sí èyí tàbí gẹ́gẹ́ bí àfidípò, ẹ tún lè lo ìwé olójú ewé 32 èyíkéyìí tá a tò sínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti oṣù August 2011. December: Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí. Bí àwọn ọmọdé bá wà nínú ilé náà, kẹ́ ẹ lo ìwé Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà tàbí Ìwé Ìtàn Bíbélì.

◼ Ọ̀sẹ̀ April 2, la máa sọ àkànṣe àsọyé tó wà fún sáà Ìrántí Ikú Kristi ti ọdún 2012. A máa ṣe ìfilọ̀ àkòrí àsọyé náà tó bá yá. Kí ìjọ kankan má ṣe sọ àsọyé yìí ṣáájú ọjọ́ Ìrántí Ikú Kristi.

◼ Àwọn akéde tó bá fẹ́ ṣe aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ ní oṣù March, ọdún 2012, máa ní àǹfààní láti pinnu bóyá ọgbọ̀n [30] wákàtí tàbí àádọ́ta [50] wákàtí làwọn máa ṣe ní oṣù náà. Láfikún sí i, láwọn ìjọ tí alábòójútó àyíká bá bẹ̀ wò ní oṣù March, gbogbo àwọn tó bá ń ṣe aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ lóṣù yẹn, yálà ọgbọ̀n [30] wákàtí tàbí àádọ́ta [50] wákàtí ni wọ́n pinnu láti ṣe, ló máa láǹfààní láti wà ní ìpàdé tí alábòójútó àyíká máa bá àwọn aṣáájú-ọ̀nà déédéé ṣe, wọ́n sì máa wà níbẹ̀ látìbẹ̀rẹ̀ dópin.

◼ Bẹ̀rẹ̀ láti oṣù September, àkòrí àsọyé fún gbogbo ènìyàn tí àwọn alábòójútó àyíká yóò máa sọ ni “Dara Pọ̀ Mọ́ Àwọn Èèyàn Ọlọ́run Tí Wọ́n Jẹ́ Aláyọ̀.”

◼ A fẹ́ láti rán yín létí pé, ẹnikẹ́ni kò gbọ́dọ̀ lo àdírẹ́sì ẹ̀ka ọ́fíìsì fún lẹ́tà tó bá kọ sáwọn èèyàn. Èyí kan àwọn lẹ́tà àtàwọn ìwé tẹ́ ẹ bá fi ránṣẹ́ láti jẹ́rìí fún àwọn olùfìfẹ́hàn, àwọn tí ẹ kò bá nílé tàbí àwọn tó ń gbé ní ibi tí kò rọrùn láti dé. Akéde kan lè fẹ́ láti lo àdírẹ́sì tí òun fúnra rẹ̀ fi ń gba lẹ́tà, níwọ̀n bí iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ ti ní í ṣe pẹ̀lú ìjọsìn rẹ̀ sí Ọlọ́run. (Mát. 28:19, 20; Róòmù 10:14, 15) Àmọ́ ṣá o, bí akéde kan bá rí i pé kò ní bọ́gbọ́n mu láti lo àdírẹ́sì tí òun fi ń gba lẹ́tà nígbà tó bá ń jẹ́rìí nípasẹ̀ lẹ́tà kíkọ, ó lè lo orúkọ rẹ̀ àti àdírẹ́sì Gbọ̀ngàn Ìjọba.—Wo Àpótí Ìbéèrè tó wà nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti oṣù May, ọdún 2002.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́