Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ October 3
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ OCTOBER 3
Orin 133 àti Àdúrà
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
bt orí 10 ìpínrọ̀ 10 sí 21 (25 min.)
Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Òwe 1-6 (10 min.)
No. 1: Òwe 6:1-19 (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Báwo Ni Róòmù 8:26, 27 Ṣe Mú Un Dá Wa Lójú Pé Ọlọ́run Nífẹ̀ẹ́ Wa? (5 min.)
No. 3: Ìyè Lórí Ilẹ̀ Ayé Kì Yóò Dópin Láé—td 25B (5 min.)
Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
5 min: Àwọn Ìfilọ̀.
10 min: Kí La Rí Kọ́? Ìjíròrò. Ẹ ka Lúùkù 5:12, 13 àti Lúùkù 8:43-48. Jíròrò bí ìtàn yìí ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa.
10 min: Àwọn Ọ̀ràn Tó Ń Fẹ́ Àbójútó Nínú Ìjọ.
10 min: Máa Hùwà Tó Bójú Mu Lóde Ẹ̀rí. (2 Kọ́r. 6:3) Lo àwọn ìbéèrè tó wà nísàlẹ̀ yìí láti jíròrò apá yìí. (1) Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká máa hùwà tó bójú mu nígbà tá a bá wà lóde ẹ̀rí? (2) Báwo la ṣe lè máa hùwà tó bójú mu (a) bí àwùjọ wa bá dé ibi tá a ti máa ṣiṣẹ́? (b) tá a bá ń rìn láti ilé dé ilé? (d) tá a bá dúró lẹ́nu ọ̀nà? (e) bí ẹni tá a jọ ṣiṣẹ́ bá ń wàásù lọ́wọ́? (ẹ) bí ẹni tá à ń wàásù fún bá ń sọ̀rọ̀? (f) bí ọwọ́ ẹni tá a fẹ́ wàásù fún bá dí tàbí tí ojú ọjọ́ kò bá dára? (g) bí ẹni tá a fẹ́ wàásù fún bá jẹ́ ọ̀yájú?
Orin 16 àti Àdúrà