Orin 61
Irú Ènìyàn Tó Yẹ Kí N Jẹ́
Bíi Ti Orí Ìwé
1. Jèhófà, kí ni ǹ bá fi san ọ̀pọ̀
Oore rẹ tóo ṣe ní ìgbésí ayé mi?
Mo fi Ọ̀rọ̀ rẹ wo ọkàn mi bíi dígí;
Jọ̀ọ́ jẹ́ nlè mọrú ẹni tí mo jẹ́ dáadáa.
Mo ṣèlérí pé màá fayé mi sìn ọ́,
Ṣùgbọ́n tipátipá kọ́ ni mo fi ńsìn ọ́.
Mo pinnu láti sìn tọkàntọkàn ni.
Ó wu èmi náà kí nmúnú rẹ dùn.
2. Ràn mí lọ́wọ́ kí nlè yẹ ara mi wò,
Kí nlè mọrú ẹni tí ó wù ọ́ kí njẹ́.
Àwọn adúróṣinṣin lo máa ńdúró tì;
Jẹ́ nlè wà lára àwọn tó ńmọ́kàn rẹ yọ̀.
(Tún wo Sm. 18:25; 116:12; 119:37; Òwe 11:20.)