Orin 16
Ẹ Sá Wá Sábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run!
1. Ẹ wá Jèhófà, ẹ̀yin onírẹ̀lẹ̀;
Wá òdodo, ọkàn tútù lónìí.
Ká lè pa yín mọ́ lọ́jọ́ ìbínú rẹ̀.
Tí ẹ ó sì wà láìléwu.
(ÈGBÈ)
Sá wá sábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run;
Dúró gbọn-in gbọn-in sọ́dọ̀ rẹ̀.
Wàá rí ààbò àtìbùkún gbà níbẹ̀;
Yára tẹ̀ lé àṣẹ rẹ̀.
2. Ẹ̀yin tóùngbẹ òótọ́ àtòdodo ńgbẹ;
Èé ṣe tẹ́ẹ tún ńdúró tẹ́ẹ̀ ńkérora?
Jẹ́ kí Jáà gbà yín lọ́wọ́ amúnisìn,
Tẹrí ba fún Kristi Ọba.
(ÈGBÈ)
Sá wá sábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run;
Dúró gbọn-in gbọn-in sọ́dọ̀ rẹ̀.
Wàá rí ààbò àtìbùkún gbà níbẹ̀;
Yára tẹ̀ lé àṣẹ rẹ̀.
3. Ẹ wòkè, ẹ fayọ̀ gbórí yín sókè;
Wo àmì pé Ìjọba náà ti dé!
Gba ìmọ́lẹ̀ òótọ́ tí Jèhófà ńtàn,
Òun nìkan ni kẹ́ẹ máa bẹ̀rù!
(ÈGBÈ)
Sá wá sábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run;
Dúró gbọn-in gbọn-in sọ́dọ̀ rẹ̀.
Wàá rí ààbò àtìbùkún gbà níbẹ̀;
Yára tẹ̀ lé àṣẹ rẹ̀.
(Tún wo Sm. 59:16; Òwe 18:10; 1 Kọ́r. 16:13.)