Orin 38
Ju Ẹrù Ìnira Rẹ Sọ́dọ̀ Jèhófà
Bíi Ti Orí Ìwé
(Sáàmù 55)
1. Jọ̀ọ́ fetí sí mi Jèhófà,
Jẹ́ kí nrójú rere rẹ.
Gbọ́ àdúrà mi, sì dáhùn;
Má ṣe jẹ́ kẹ́rù bà mí.
(ÈGBÈ)
Gbé ẹrù rẹ fún Jèhófà;
Òun náà ló lè gbé ọ ró.
Kò ní jẹ́ kẹ́sẹ̀ rẹ yẹ̀ láé,
Yóò mú ọ dúró ṣinṣin.
2. Bí mo níyẹ̀ẹ́ bí àdàbà,
Ǹ bá fò jìnnà réré,
Sáwọn tó ńlépa ẹ̀mí mi,
Pẹ̀lú ọkàn ìbínú.
(ÈGBÈ)
Gbé ẹrù rẹ fún Jèhófà;
Òun náà ló lè gbé ọ ró.
Kò ní jẹ́ kẹ́sẹ̀ rẹ yẹ̀ láé,
Yóò mú ọ dúró ṣinṣin.
3. Èmi yóò ké pe Jèhófà,
Ààbò rẹ̀ ni mo ńtọrọ.
Ó ńfún mi nífọ̀kànbalẹ̀,
Àtokun tí mo nílò.
(ÈGBÈ)
Gbé ẹrù rẹ fún Jèhófà;
Òun náà ló lè gbé ọ ró.
Kò ní jẹ́ kẹ́sẹ̀ rẹ yẹ̀ láé,
Yóò mú ọ dúró ṣinṣin.