Àwọn Ìfilọ̀
◼ Ìwé tá a máa lò ní September àti October: Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! November àti December: Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?, Ṣé Wàá Fẹ́ Mọ Òtítọ́?, tàbí èyíkéyìí lára àwọn ìwé àṣàrò kúkúrú tí ìjọ bá ní lọ́wọ́.
◼ Ọ̀sẹ̀ April 21 la máa sọ àkànṣe àsọyé fún gbogbo èèyàn ní àkókò Ìrántí Ikú Kristi ti ọdún 2014. A máa ṣe ìfilọ̀ àkòrí àsọyé náà tó bá yá. Kí àwọn ìjọ tó bá ní ìbẹ̀wò alábòójútó àyíká, àpéjọ àyíká tàbí àpéjọ àkànṣe ní òpin ọ̀sẹ̀ yẹn sọ àkànṣe àsọyé wọn ní ọ̀sẹ̀ tó bá tẹ̀ lé e. Kí ìjọ kankan má ṣe sọ àsọyé yìí ṣáájú April 21.