Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ October 7
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ OCTOBER 7
Orin 92 àti Àdúrà
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
jr orí 15 ìpínrọ̀ 1 sí 6 àti àpótí tó wà lójú ìwé 184 (30 min.)
□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Éfésù 1-6 (10 min.)
No. 1: Éfésù 4:1-16 (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Ohun Tó Túmọ̀ sí Láti Wá Òdodo Ọlọ́run Lákọ̀ọ́kọ́—Mát. 6:33 (5 min.)
No. 3: Kí Ni Ọ̀rọ̀ Náà “Ṣọ́ọ̀ṣì” Túmọ̀ Sí?—td 43A (5 min.)
□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
10 min: Àwọn Àbá Tá A Lè Lò Láti Fi Ìwé Ìròyìn Lọni Lóṣù October. Ìjíròrò. Fi ààbọ̀ ìṣẹ́jú sí ìṣẹ́jú kan sọ ìdí táwọn èèyàn fi máa nífẹ̀ẹ́ sí àwọn ìwé ìròyìn náà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù yín. Lẹ́yìn náà, lo àwọn àpilẹ̀kọ tó dá lórí àkòrí Ilé Ìṣọ́ October, kó o sì ní kí àwọn ará sọ àwọn ìbéèrè tó lè mú kí àwọn èèyàn nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ wọn. Lẹ́yìn náà, kí wọ́n sọ ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí wọ́n lè fi ti ọ̀rọ̀ wọn lẹ́yìn. Ohun kan náà ni kó o ṣe nípa àwọn àpilẹ̀kọ tó dá lórí àkòrí Jí! September–October. Bí àkókò bá ṣì wà, ẹ tún lè jíròrò àpilẹ̀kọ mìíràn nínú ọ̀kan lára àwọn ìwé ìròyìn náà. Ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè fi ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ìwé ìròyìn náà lọni.
10 min: Ohun tó ń fẹ́ àbójútó nínú ìjọ.
10 min: Àwọn Tí Ń Ṣiṣẹ́ Kára. (1 Tẹs. 5:12, 13) Fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu alàgbà méjì. Àwọn iṣẹ́ wo ni wọ́n ń bójú tó nínú ìjọ àti nínú ètò Ọlọ́run? Báwo ni wọ́n ṣe ń ráyè bójú tó àwọn iṣẹ́ náà láfikún sí iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ wọn àti àwọn ojúṣe wọn nínú ìdílé? Báwo ni wọ́n ṣe fi iṣẹ́ òjíṣẹ́ sípò àkọ́kọ́? Báwo ni ìdílé wọn ṣe ń tì wọ́n lẹ́yìn?
Orin 123 àti Àdúrà