Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tá A Lè Lò
Láti Bẹ̀rẹ̀ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ní Sátidé Àkọ́kọ́ Lóṣù February
“Oríṣiríṣi èrò ni àwọn tí à ń bá sọ̀rọ̀ ní nípa Bíbélì. Àwọn kan gbà gbọ́ pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni, àmọ́ àwọn míì rò pé kò yàtọ̀ sáwọn ìwé míì. Kí lèrò rẹ nípa Bíbélì?” Jẹ́ kó fèsì. Fi ẹ̀yìn Ilé Ìṣọ́ February 1 hàn án, kí ẹ jíròrò ohun tá a kọ sábẹ́ ìbéèrè àkọ́kọ́, kí ẹ si ka ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan ó kéré tán. Fún un ní ìwé ìròyìn náà, kí o sì ṣètò láti pa dà wá jíròrò ìbéèrè tó tẹ̀ lé e.
Ilé Ìṣọ́ February 1
“Ọ̀pọ̀ èèyàn ló wù pé kí ogun kásẹ̀ nílẹ̀. Ǹjẹ́ o rò pé ó ṣeé ṣe kí àlàáfíà wà kárí ayé? [Jẹ́ kó fèsì.] Gbọ́ ìlérí tí Ìwé Mímọ́ ṣe. [Ka Sáàmù 46:9.] Ó dùn mọ́ni pé, àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó wáyé nígbà Ogun Àgbáyé Kìíní àtàwọn ohun tó ti ń ṣẹlẹ̀ látìgbà náà mú kó dá wa lójú pé láìpẹ́ Ọlọ́run máa mú àsọtẹ́lẹ̀ yìí ṣẹ, ó sì máa mú kí ogun kásẹ̀ nílẹ̀ títí láé. Ìwé ìròyìn yìí ṣàlàyé bí èyí ṣe máa ṣẹlẹ̀.”
Ji! January–February
“Gbogbo wa la fẹ́ kí ìgbéyàwó wa túbọ̀ ládùn kí ohunkóhun má sì bà á jẹ́. Ǹjẹ́ o mọ bó o ṣe lè ṣe é? [Jẹ́ kó fèsì.] Ìlànà Bíbélì yìí ṣàlàyé bó o ṣe lè ṣe é. [Ka Jákọ́bù 1:19.] Tó o bá ń fara balẹ̀ tẹ́tí sí ọkọ tàbí aya rẹ ó fi hàn pé o nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ dénú. Àpilẹ̀kọ tó bẹ̀rẹ̀ lójú ìwé 12 nínú ìwé ìròyìn yìí sọ àwọn ìlànà Bíbélì míì tó lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè máa fetí sílẹ̀ dáadáa, kí ìgbéyàwó rẹ sì lè túbọ̀ ládùn.”