Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ February 10
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ FEBRUARY 10
Orin 57 àti Àdúrà
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
cl orí 2 ìpínrọ̀ 21 sí 24 àti àpótí tó wà lójú ìwé 24 (30 min.)
Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Jẹ́nẹ́sísì 25-28 (10 min.)
No. 1: Jẹ́nẹ́sísì 25:19-34 (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Ìjọba Ọlọ́run Yóò Mú Àìsàn Kúrò Pátápátá—td 32B (5 min.)
No. 3: Olùkọ́ Ńlá Náà Sin Àwọn Ẹlòmíràn—lr orí 6(5 min.)
Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
15 min: Kí La Rí Kọ́? Ìjíròrò. Ẹ ka Jòhánù 4:6-26. Ẹ jíròrò bí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa.
15 min: “Mú Kí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Sunwọ̀n Sí I—Máa Ṣàkọsílẹ̀ Àwọn Tó Fìfẹ́ Hàn.” Ìjíròrò. Tẹ́ ẹ bá ń jíròrò kókó kọ̀ọ̀kan tó wà lábẹ́ ìsọ̀rí náà “Bó O Ṣe Lè Ṣe É,” ní kí àwọn ará sọ ìdí tí àwọn àbá náà fi wúlò.
Orin 98 àti Àdúrà