Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tá A Lè Lo
Láti Bẹ̀rẹ̀ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ní Saturday Àkọ́kọ́ Lóṣù June
“Gbogbo wa la ní mọ̀lẹ́bí tàbí ọ̀rẹ́ kan tó ti ṣaláìsí. Ǹjẹ́ o nírètí pé o tún lè pa dà rí wọn? [Jẹ́ kó fèsì.] Gbọ́ ọ̀rọ̀ ìtùnú yìí.” Ẹ jọ ka àwọn ìsọfúnni tó wà lábẹ́ ìsọ̀rí àkọ́kọ́ lójú ìwé 16 nínú Ilé Ìṣọ́ June 1 àti ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan tí wọ́n tọ́ka sí. Fún un ní ìwé ìròyìn náà, kó o sì ṣètò láti pa dà lọ jíròrò ìdáhùn sí ìbéèrè tó kàn.
Ilé Ìṣọ́ June 1
“Ọ̀pọ̀ lára wa ló ń tiraka láti lè rówó gbọ́ bùkátà, àwọn ẹlòmíì kò tiẹ̀ ní àwọn ohun kòṣeémáàní ìgbésí ayé. Ǹjẹ́ o rò pé àkókò kan lè wà tí kò ní sí ẹnì kankan tó máa jẹ́ òtòṣì? [Jẹ́ kó fèsì. Kó o wá ka Sáàmù 9:18.] Ìwé ìròyìn yìí sọ ohun tó fa ipò òṣì, ó sì tún sọ ohun tí Bíbélì sọ nípa bí ìṣòro náà ṣe máa yanjú.”
Ji! April–June
“Àwọn tá a yàn láti lo àkókò pẹ̀lú wọn máa ń nípa lórí ọ̀nà tá à ń gbà sọ̀rọ̀, ọ̀nà tá à ń gbà ronú àti ohun tá à ń ṣe. Ǹjẹ́ èyí mú kó o túbọ̀ mọyì ohun tí ẹsẹ Bíbélì yìí sọ? [Ka 1 Kọ́ríńtì 15:33. Kó o wá jẹ́ kó fèsì.] Àpilẹ̀kọ tó wà lójú ìwé 24 nínú Jí! yìí ran àwọn ọmọdé lọ́wọ́ láti ronú lórí bí wọ́n ṣe ń pẹ́ tó nídìí lílo àwọn ohun tó ń gbé ìsọfúnni jáde, ó sì tún pèsè ìtọ́sọ́nà lórí bí àwọn òbí ṣe lè ràn wọ́n lọ́wọ́.”