ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • mrt àpilẹ̀kọ 34
  • Ìgbà Wo La Máa Bọ́ Lọ́wọ́ Àwọn Afẹ̀míṣòfò?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìgbà Wo La Máa Bọ́ Lọ́wọ́ Àwọn Afẹ̀míṣòfò?
  • Àkójọ Àpilẹ̀kọ àti Fídíò
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ṣé inú Ọlọ́run ń dùn sáwọn tó ń fẹ̀mí ṣòfò?
  • Ohun tó fà á táwọn kan fi máa ń fẹ̀mí àwọn èèyàn ṣòfò
  • Ìgbà tá a máa bọ́ lọ́wọ́ àwọn afẹ̀míṣòfò
  • Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tá A Lè Lo
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2011
  • “Ẹ Má Fòyà Tàbí Kí Ẹ Jáyà”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2003
  • Àwọn Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Yìí
    Jí!—2011
  • Ohun Tó O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2006
Àwọn Míì
Àkójọ Àpilẹ̀kọ àti Fídíò
mrt àpilẹ̀kọ 34
Panápaná kan ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ níbi ilé kan tó wó.

Ìgbà Wo La Máa Bọ́ Lọ́wọ́ Àwọn Afẹ̀míṣòfò?

Táwọn afẹ̀míṣòfò bá ṣọṣẹ́, ó ṣeé ṣe kó o máa ṣe kàyéfì pé: ‘Ṣé Ọlọ́run tiẹ̀ rí gbogbo ohun tó ń ṣẹlẹ̀ yìí? Kí ló dé tírú àwọn nǹkan báyìí fi ń ṣẹlẹ̀? Ìgbà wo la máa bọ́ lọ́wọ́ àwọn afẹ̀míṣòfoa? Kí lá jẹ́ kọ́kàn mi balẹ̀ láìka gbogbo ohun tó ń ṣẹlẹ̀ yìí sí?’ Bíbélì dáhùn àwọn ìbéèrè yìí lọ́nà tó ń fini lọ́kàn balẹ̀.

Ṣé inú Ọlọ́run ń dùn sáwọn tó ń fẹ̀mí ṣòfò?

Ọlọ́run kórìíra ìwà ipá àti fífi ẹ̀mí èèyàn ṣòfò. (Sáàmù 11:5; Òwe 6:16, 17) Jésù tí Ọlọ́run rán wá sáyé náà bá àwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀ wí nígbà tí wọ́n fa idà yọ láti gbèjà Jésù. (Mátíù 26:50-52) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn kan máa ń sọ pé Ọlọ́run fọwọ́ sí báwọn ṣe ń pààyàn, àmọ́ Ọlọ́run ò fọwọ́ sí irú nǹkan bẹ́ẹ̀. Kódà, Ọlọ́run kì í tẹ́tí sí àdúrà wọn.—Àìsáyà 1:15.

Ó máa ń dun Ọlọ́run tó bá rí àwọn tó ń jìyà, títí kan àwọn táwọn afẹ̀míṣòfò ṣe lọ́ṣẹ́. (Sáàmù 31:7; 1 Pétérù 5:7) Bíbélì tún jẹ́ ká mọ̀ pé Ọlọ́run máa tó fòpin sí ìwà ipá.—Àìsáyà 60:18.

Ohun tó fà á táwọn kan fi máa ń fẹ̀mí àwọn èèyàn ṣòfò

Bíbélì sọ ohun tó fa ìwà burúkú yìí, ó ní: “Èèyàn ti jọba lórí èèyàn sí ìpalára rẹ̀.” (Oníwàásù 8:⁠9) Ọjọ́ pẹ́ táwọn tó wà nípò àṣẹ ti máa ń lo ọwọ́ agbára àti ìwà ipá láti tẹ àwọn èèyàn lórí ba. Bójọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, àwọn tí wọ́n ń jẹ gàba lé lórí lè yarí, wọ́n sì lè bẹ̀rẹ̀ sí í pa àwọn èèyàn kí wọ́n lè fi ìhónú hàn.—Oníwàásù 7:7.

Ìgbà tá a máa bọ́ lọ́wọ́ àwọn afẹ̀míṣòfò

Ọlọ́run ṣèlérí pé òun máa fòpin sí ìwà ipá àti ìbẹ̀rù, òun á sì mú kí àlàáfíà jọba kárí ayé. (Àìsáyà 32:18; Míkà 4:3, 4) Lára ohun tó máa ṣe ni pé:

  • Ó máa fòpin sí ohun tó ń mú káwọn èèyàn hùwà ipá. Ọlọ́run máa fi ìjọba ẹ̀ rọ́pò ìjọba èèyàn. Jésù Kristi tó jẹ́ Ọba Ìjọba náà ò ní ṣojúsàájú tàbí kó gbè sẹ́yìn ẹnì kan, á sì fòpin sí ìnilára àti ìwà ipá. (Sáàmù 72:2, 14) Tó bá dìgbà yẹn, kò sẹ́ni táá máa hùwà ipá mọ́. Bíbélì sọ pé: “Inú [àwọn èèyàn] yóò sì máa dùn jọjọ nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àlàáfíà.”—Sáàmù 37:10, 11.

  • Ó máa mú gbogbo ohun tí ìwà ipá ti fà kúrò. Gbogbo àwọn táwọn afẹ̀míṣòfò ti ṣe léṣe ni Ọlọ́run máa mú lára dá, á sì pẹ̀tù sọ́kàn àwọn tí wọ́n ti kó ẹ̀dùn ọkàn bá. (Àìsáyà 65:17; Ìfihàn 21:3, 4) Ó tún ṣèlérí pé òun máa jí àwọn tó ti kú díde, wọ́n á sì gbádùn àlàáfíà lórí ilẹ̀ ayé.—Jòhánù 5:28, 29.

Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé kò ní pẹ́ mọ́ tí Ọlọ́run á fi ṣe àwọn nǹkan yìí. Àmọ́ o lè máa ronú pé, ‘Kí ló dé tí Ọlọ́run fi ń dúró kó tó fòpin sí ìwà burúkú yìí?’ Kó o lè rí ìdáhùn sí ìbéèrè ẹ, wo fídíò náà Kí Nìdí Tí Ọlọ́run Fi Gbà Pé Ká Máa Jìyà?

a “Àwọn afẹ̀míṣòfò” làwọn tó máa ń hùwà ipá sáwọn èèyàn, tí wọ́n sì máa ń kó ìpayà bá àwọn aráàlú, torí pé wọ́n fẹ́ kí ìyípadà wáyé lórí ọ̀rọ̀ òṣèlú, ìsìn tàbí àwọn nǹkan míì láwùjọ. Àmọ́, táwọn kan bá hùwà ipá, ẹnu àwọn èèyàn kì í kò lórí bóyá afẹ̀míṣòfò ni wọ́n tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́.

Bíbélì ti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti fara dà á

Méjì lára ohun tí Bíbélì sọ pé ó lè ràn wá lọ́wọ́ rèé.

  • Gbàdúrà sí Ọlọ́run.—Fílípì 4:6, 7.

  • Jẹ́ kí ìrètí tó wà nínú Bíbélì fi ẹ́ lọ́kàn balẹ̀.—Hébérù 6:19.

Tó o bá fẹ́ mọ àwọn nǹkan míì tí Bíbélì sọ pé a lè ṣe, ka àpilẹ̀kọ náà “Bó O Ṣe Lè Borí Àníyàn.”

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ti fojú winá ìjàǹbá táwọn afẹ̀míṣòfò ṣe ti rí ìtùnú látọ̀dọ̀ àwọn tí wọ́n jọ ń sin Ọlọ́run. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ méjì yìí:

  • Ibi ìrántí kan níwájú ilé ìwé kan ní Beslan, Rọ́ṣíà.

    Natalya àtọmọ ẹ̀ Aslan tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́sàn-án wà nílé ìwé kan ní Beslan, lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà nígbà táwọn afẹ̀míṣòfò tó dira ogun já wọlé, tí wọ́n sì kó àwọn èèyàn tó lé ní ẹgbẹ̀rún kan (1,000) lọ. Ó dunni pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn èèyàn ni wọ́n pa, èyí tó sì pọ̀ jù lára wọn ló jẹ́ ọmọdé. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Natalya àti Aslan là á já, síbẹ̀ ẹ̀dùn ọkàn tó bá wọn kọjá àfẹnusọ. Ka ohun tó ràn wọ́n lọ́wọ́ láti borí ẹ̀dùn ọkàn náà.

  • Pablo àti Sophie.

    Pablo àti Sophie pàdánù ọmọ wọn nígbà táwọn afẹ̀míṣòfò kọlu ilé gogoro méjì nílùú New York. Wo fídíò yìí kó o lè mọ ohun tó ran àwọn àtàwọn míì lọ́wọ́ láti borí ẹ̀dùn ọkàn tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà fà.

Bíbélì ti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti yí pa dà

Ọ̀pọ̀ ni inú máa ń bí tí wọ́n bá rí i táwọn tó wà nípò agbára bá ń fi ọwọ́ ọlá gbá àwọn míì lójú, tí wọ́n sì ń jẹ gàba lórí wọn. Torí náà, wọ́n lè ronú pé àfi káwọn jà, káwọn sì fẹ̀mí ọ̀pọ̀ ṣòfò kí ìṣòro náà tó lè yanjú. Ṣé irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ lè yí pa dà? Bẹ́ẹ̀ ni. Tó o bá fẹ́ mọ bí Bíbélì ṣe ran àwọn kan lọ́wọ́ láti yí pa dà, ka àpilẹ̀kọ náà “Ṣé A Máa Bọ́ Lọ́wọ́ Àwọn Afẹ̀míṣòfò Láyé Yìí?” lédè Gẹ̀ẹ́sì.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́