Ohun Tó O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn
Ile Iṣọ May 15
“Ṣó o rò pé wàá dé inú ayé tí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí sọ? [Ka 2 Pétérù 3:13. Kó o wá jẹ́ kó fèsì.] Ìwé ìròyìn yìí sọ bí ọ̀run tuntun àti ayé tuntun ṣe máa rí. Ó tún ṣàlàyé bí ìgbésí ayé ṣe máa yàtọ̀ nígbà tí ìlérí Ọlọ́run bá ṣẹ lórí ilẹ̀ ayé.”
Ile Iṣọ June 1
“Nígbà kan rí, èyí tó pọ̀ lára àwọn àṣà ìbílẹ̀ ló kọ́ni pé ká máa bọ̀wọ̀ fágbà gẹ́gẹ́ bí òfin ayé ọjọ́un yìí ṣe sọ. [Ka Léfítíkù 19:32.] Ǹjẹ́ o rò pé àwọn èèyàn ṣì ń bọ̀wọ̀ fágbà bẹ́ẹ̀ lóde òní? [Jẹ́ kó fèsì.] Ìwé ìròyìn yìí jíròrò bí Ọlọ́run ṣe ń bójú tó àwọn àgbàlagbà, ó sì tún sọ bí àwa náà ṣe lè bójú tó wọn.”
Jí Apr.-June
“Ọ̀pọ̀ ọlọ́run làwọn èèyàn ń jọ́sìn lónìí. Síbẹ̀, kíyè sí ohun tí Jésù sọ nípa Bàbá rẹ̀ ọ̀run nígbà tó ń gbàdúrà. [Ka Jòhánù 17:3.] Bó bá wá jẹ́ pé Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo ló wà, ààyè wo la wá fẹ́ to àwọn ọlọ́run tó kù sí? [Jẹ́ kó fèsì.] Àpilẹ̀kọ yìí ṣàlàyé ojú ìwòye Bíbélì.” Fi àpilẹ̀kọ tó wà lójú ìwé 26 sí 27 hàn án.
“Ọ̀pọ̀ èèyàn ló gbà gbọ́ pé Jésù ni Ọlọ́run. Àmọ́, ọmọlẹ́yìn Jésù kan, ìyẹn Pétérù pe Jésù ní Ọmọ Ọlọ́run. [Ka Mátíù 16:16.] Ṣó o rò pé ó ṣeé ṣe kí Jésù jẹ́ Ọlọ́run kó sì tún jẹ́ pé òun kan náà ni Ọmọ Ọlọ́run? [Jẹ́ kó fèsì.] Àpilẹ̀kọ tó wà lójú ìwé 28 sí 29 nínú ìwé ìròyìn yìí ṣe àgbéyẹ̀wò ìbéèrè yìí ó sì ṣàlàyé ojú ìwòye Bíbélì.”