ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 5/11 ojú ìwé 4
  • Àwọn Ìfilọ̀

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Ìfilọ̀
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2011
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2011
km 5/11 ojú ìwé 4

Àwọn Ìfilọ̀

◼ Ìwé tá a máa lò ní May: Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! Nígbà tẹ́ ẹ bá ń ṣe ìpadàbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn tó fìfẹ́ hàn tó fi mọ́ àwọn tó wá síbi Ìrántí Ikú Kristi tàbí àwọn àpéjọ míì tí ètò Ọlọ́run ṣètò àmọ́ tí wọn kò tíì máa dara pọ̀ mọ́ ìjọ déédéé, ẹ fún wọn ní ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Kẹ́ ẹ sì ní in lọ́kàn láti fi bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú wọn. June: Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Bí onílé bá ti ní ìwé yìí, ẹ fún un ní ìwé èyíkéyìí tí ọjọ́ rẹ̀ ti pẹ́ tí ìjọ bá ní lọ́wọ́. Ẹ tún lè lo Jọ́sìn Ọlọ́run Tòótọ́ Kan Ṣoṣo Náà gẹ́gẹ́ bí àfidípò. July àti August: Ẹ lè lo èyíkéyìí lára àwọn ìwé olójú ìwé 32 tó bá wà lọ́wọ́ tí àwọn èèyàn máa ń nífẹ̀ẹ́ sí ní ìpínlẹ̀ ìwàásù yín: Akoso Naa Ti Yoo Mu Paradise Wá, Ẹ Máa Ṣọ́nà!, Gbádùn Iwalaaye lori Ilẹ Ayé Titilae!, Ìgbàgbọ́ Òdodo Ló Máa Mú Kó O Ní Ayọ̀ (ó máa fa àwọn Mùsùlùmí mọ́ra), Iwọ Ha Nilati Gbàgbọ́ Ninu Mẹtalọkan Bí?, Ìwọ Lè Di Ọ̀rẹ́ Ọlọ́run!, Ki Ni Ète Igbesi-Aye—Bawo Ni Iwọ Ṣe Le Rí I?, Kí Ní Ń Ṣẹlẹ̀ sí Wa Nígbà tí A Bá Kú?, Nígbà Tí Ẹnìkan Tí Ìwọ Fẹ́ràn Bá Kú, Orukọ Atọrunwa naa Tí Yoo Wà Titilae, Ọlọrun Ha Bikita Nipa Wa Niti Gidi Bi?, àti “Sawo o! Emi Nsọ Ohun Gbogbo Di Ọtun”.

◼ Ní Friday, May 27, ọdún 2011, kò ní sáyè fún wa láti gbàlejò ní Bẹ́tẹ́lì. Ẹ jọ̀wọ́, ẹ má ṣèbẹ̀wò, bẹ́ẹ̀ ni kẹ́ ẹ má ṣe wá gba ìwé lọ́jọ́ yìí.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́