Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ ní June 6
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ JUNE 6
Orin 68 àti Àdúrà
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
bt orí 4 ìpínrọ̀ 13 sí 20, àti àpótí tó wà lójú ìwé 34 (25 min.)
□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Sáàmù 34-37 (10 min.)
No. 1: Sáàmù 35:1-18 (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Ṣé Ó Yẹ Ká Gba Ẹ̀mí Wa Là Láìka Ohun Tó Lè Ná Wa Sí?—td 11B (5 min.)
No. 3: Ẹ̀kọ́ Wo La Lè Rí Kọ́ Látinú Lúùkù 12:13-15, 21? (5 min.)
□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
5 min: Àwọn Ìfilọ̀.
10 min: Lo Ìbéèrè Láti Kọ́ni Lọ́nà tó Múná Dóko—Apá 2. Ìjíròrò tó dá lórí ìwé Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, ojú ìwé 237, ìpínrọ̀ 3 sí ojú ìwé 238, ìpínrọ̀ 5. Ní ṣókí ṣe àṣefihàn kókó kan tàbí méjì látinú àpilẹ̀kọ náà.
10 min: Àwọn Ọ̀ràn Tó Ń Fẹ́ Àbójútó Nínú Ìjọ.
10 min: Àwọn Àṣeyọrí Wo La Ṣe? Ìjíròrò. Alábòójútó iṣẹ́ ìsìn ni kó ṣe apá yìí. Gbóríyìn fún ìjọ fún ìgbòkègbodò wọn lásìkò Ìrántí Ikú Kristi, kó o sì sọ àwọn àṣeyọrí tẹ́ ẹ ṣe. Ní kí àwọn ará sọ àwọn ìrírí tí wọ́n ní nígbà tí wọ́n ṣe aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ lóṣù March, April àti May.
Orin 83 àti Àdúrà