Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ June 13
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ JUNE 13
Orin 45 àti Àdúrà
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
bt orí 5, ìpínrọ̀ 1 sí 8 àti àpótí tó wà lójú ìwé 39 (25 min.)
□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Sáàmù 38-44 (10 min.)
No. 1: Sáàmù 41:1–42:5 (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Àpẹẹrẹ Àwọn Ọ̀rẹ́ Àtàtà Tó Wà Nínú Bíbélì àti Àwọn Ànímọ́ Tó Yẹ Ká Ní (5 min.)
No. 3: Àkókò Wo Ni Ìgbà Àwọn Kèfèrí Dópin?—td 30A (5 min.)
□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
5 min: Àwọn Ìfilọ̀.
10 min: Àwọn Ọ̀nà Tá À Ń Gbà Wàásù Ìhìn Rere—Dídarí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ìjíròrò tá a gbé ka ìwé A Ṣètò Wa ojú ìwé 98, ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 99, ìpínrọ̀ 1. Ní kí àwọn ará sọ ayọ̀ tí wọ́n ti rí látinú kíkọ́ ẹnì kan lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, tí ẹni náà sì ń tẹ̀síwájú nípa tẹ̀mí. Kó tó di ọjọ́ náà, o lè ti sọ fún ẹnì kan tàbí méjì pé kí wọ́n múra sílẹ̀ láti sọ̀rọ̀.
10 min: Ìlànà Wo Ni Àwọn Kristẹni Gbọ́dọ̀ Máa Tẹ̀ Lé Lórí Ọ̀ràn Ìgbéyàwó, Ìkọ̀sílẹ̀ àti Ìpínyà? Alàgbà ni kó sọ àsọyé yìí. A gbé e ka ìwé A Ṣètò Wa, ojú ìwé 195, ìbéèrè 1 sí 3.
10 min: “Sùúrù La Fi Ń Ṣe Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Wa.” Ìbéèrè àti ìdáhùn.
Orin 103 àti Àdúrà