Àwọn Ìfilọ̀
◼ Ìwé tá a máa lò ní May àti June: Ẹ lo àwọn ìwé àṣàrò kúkúrú tẹ́ ẹ bá ní lọ́wọ́. Bí onílé bá nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ wa, ẹ fi bá a ṣe ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì hàn án. Kí ẹ lo ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni, Tẹ́tí sí Ọlọ́run tàbí Tẹ́tí sí Ọlọ́run Kó O Lè Wà Láàyè Títí Láé. July àti August: Ìwe Ìròyìn Ayọ̀ Látọ̀dọ̀ Ọlọ́run! tàbí èyíkéyìí lára àwọn ìwé pẹlẹbẹ olójú ewé méjìlélọ́gbọ̀n yìí: Tẹ́tí sí Ọlọ́run tàbí Tẹ́tí sí Ọlọ́run Kó O Lè Wà Láàyè Títí Láé tàbí Ọ̀nà Tó Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun—Ṣé O Ti Rí I? Tẹ́ ẹ bá pàdé ẹlẹ́sìn Mùsùlùmí, kí ẹ fún un ní ìwé Ìgbàgbọ́ Òdodo Ló Máa Mú Kó O Ní Ayọ̀ tàbí Ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run Ló Máa Ṣamọ̀nà Ẹ̀dá Wọ Párádísè.
◼ Bí wọ́n bá dá ẹ dúró sílé ìwòsàn, tó o sì fẹ́ káwọn alàgbà tó wà ní àdúgbò náà tàbí Ẹgbẹ́ Tó Ń Bẹ Àwọn Aláìsàn Wò mọ̀ pé o wà níbẹ̀, kí ló yẹ kó o ṣe? Jẹ́ kí àwọn aláṣẹ ilé ìwòsàn náà mọ̀ pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni ẹ́, kó o sì ṣàlàyé fún wọn pé o fẹ́ kí òjíṣẹ́ kan tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà wá bẹ̀ ọ́ wò níbẹ̀. Òfin orílẹ̀-èdè Nàìjíríà àti ìlànà ìtọ́jú ìṣègùn sọ pé kí àwọn ìlé ìwòsàn pa ohun tó o bá sọ fún wọn àti ìsọfúnni nípa ìtọ́jú tí wọ́n fún ẹ mọ́ láṣìírí. Àmọ́ ó tún sọ pé tó o bá gbà, wọ́n lè jẹ́ kí àwọn alàgbà mọ̀ pé o wà níbẹ̀, kí wọ́n sì gbà wọ́n láyè láti fún ẹ ní ìṣírí nípa tẹ̀mí.