Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ June 3
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ JUNE 3
Orin 68 àti Àdúrà
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
jr orí 10 ìpínrọ̀ 8 sí 13 (30 min.)
□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Jòhánù 17-21 (10 min.)
No. 1: Jòhánù 21:15-25 (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Kí Nìdí Tí Kò Fi Yẹ Ká “Tẹ̀ Lé Ogunlọ́gọ̀”?—Ẹ́kís. 23:2; Òwe 1:10 (5 min.)
No. 3: Ìjọba Ọlọ́run Nìkan Ló Lè Tún Ayé Ṣe—td 31E (5 min.)
□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
10 min: Àwọn Àbá Tá A Lè Lò Láti Fi Ìwé Ìròyìn Lọni Lóṣù June. Ìjíròrò. Fi ààbọ̀ ìṣẹ́jú sí ìṣẹ́jú kan tọ́ka sí àwọn àpilẹ̀kọ tó ṣeé ṣe kí àwọn èèyàn nífẹ̀ẹ́ sí ní ìpínlẹ̀ ìwàásù yín. Lẹ́yìn náà, lo àwọn àpilẹ̀kọ tó dá lórí àkòrí Ilé Ìṣọ́ June, kó o sì ní kí àwọn ará sọ àwọn ìbéèrè tó lè mú kí àwọn èèyàn nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ wọn. Lẹ́yìn náà, kí wọ́n sọ ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí wọ́n lè fi ti ọ̀rọ̀ wọn lẹ́yìn. Ohun kan náà ni kó o ṣe nípa àwọn àpilẹ̀kọ tó dá lórí àkòrí Jí! May–June 2013. Tí àkókò bá ṣì wà, ẹ tún lè jíròrò àpilẹ̀kọ mìíràn nínú ìwé ìròyìn méjèèjì. Ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè fi ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ìwé ìròyìn náà lọni.
10 min: Ìdí Tá A Fi Ń Ròyìn Iṣẹ́ Ìsìn Pápá Wa. Akọ̀wé ni kó sọ àsọyé yìí. A gbé e ka ìwé A Ṣètò Wa, ojú ìwé 88, ìpínrọ̀ 2 sí ojú ìwé 90, ìpínrọ̀ 1.
10 min: Ohun tó ń fẹ́ àbójútó nínú ìjọ.
Orin 107 àti Àdúrà