Àwọn Ìfilọ̀
◼ Ìwé tá a máa lò ní April àti May: Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! Ẹ fún ẹni tó bá nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ yín ní ìwé àṣàrò kúkúrú náà Ṣé Wàá Fẹ́ Mọ Òtítọ́?, kẹ́ ẹ sì sapá láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Nígbà tẹ́ ẹ bá ń ṣe ìpadàbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn tó wá síbi Ìrántí Ikú Kristi tàbí àwọn àpéjọ míì tí ètò Ọlọ́run ṣètò àmọ́ tí wọn kò tíì máa dara pọ̀ mọ́ ìjọ déédéé, ẹ ní in lọ́kàn láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú wọn nínú ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni. June: Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Ẹ sapá láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nígbà àkọ́kọ́ tẹ́ ẹ bá wàásù fún ẹnì kan. Bí onílé bá ti ní ìwé náà, tí kò sì fẹ́ kí á wá máa kọ́ òun lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ẹ lè fún un ní àwọn ìwé ìròyìn tí ọjọ́ wọn ti pẹ́ tàbí ìwé pẹlẹbẹ èyíkéyìí tó sọ̀rọ̀ nípa ohun tí onílé nífẹ̀ẹ́ sí. July: Ẹ lo ọ̀kan lára àwọn ìwé pẹlẹbẹ olójú ewé 32 wọ̀nyí: Tẹ́tí sí Ọlọ́run tàbí Tẹ́tí sí Ọlọ́run Kó O Lè Wà Láàyè Títí Láé, àti Ìwọ Lè Di Ọ̀rẹ́ Ọlọ́run! kẹ́ ẹ́ sì gbìyànjú láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Nígbà tẹ́ ẹ bá ń ṣe ìpadàbẹ̀wò, ẹ lè fún onílé ní ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni tàbí kẹ́ ẹ fún un ní ìwé pẹlẹbẹ èyíkéyìí tẹ́ ẹ bá rí i pé ó máa nífẹ̀ẹ́ sí.
◼ Nígbàkigbà tó o bá ń ṣètò fúnra rẹ láti rìnrìn àjò lọ sí orílẹ̀-èdè mìíràn, tó o sì fẹ́ lọ sí àpéjọ àgbègbè níbẹ̀, o lè rí ìsọfúnni tó máa wúlò fún ọ lórí Ìkànnì jw.org, o máa rí i ní ìlujá tá a pè ní “Conventions” èyí tó wà lábẹ́ abala tá a pè ní “Lookup.”