Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní May 7
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ MAY 7
Orin 120 àti Àdúrà
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
bt orí 20 ìpínrọ̀ 8 sí 15, àti àpótí tó wà lójú ìwé 161 (25 min.)
□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Jeremáyà 35-38 (10 min.)
No. 1: Jeremáyà 36:14-26 (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Ìwàláàyè Títí Láé Kì Í Ṣe Àlá Lásán—td 33A (5 min.)
No. 3: Ǹjẹ́ Ohun Tí Àwọn Èèyàn Ń Ṣe Lè Dun Ọlọ́run?—Oníd. 2:11-18 (5 min.)
□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
5 min: Àwọn Ìfilọ̀.
15 min: “Lẹ́tà Látọ̀dọ̀ Ìgbìmọ̀ Olùdarí.” Ìjíròrò tó dá lórí àpilẹ̀kọ olójú ewé méjì tó wà nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti oṣù April 2012. Ní kí àwọn ará sọ̀rọ̀ lórí ohun tó gbàfiyèsí nínú ìròyìn ọdọọdún tó wà nínú àkìbọnú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti oṣù March 2012. Tó bá ṣeé ṣe, ṣètò ṣáájú pé kí àwọn kan sọ ìrírí tó fúnni níṣìírí látinú ìwé ọdọọdún tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ìyẹn 2012 Yearbook . Parí ìjíròrò náà nípa fífún àwọn ará níṣìírí pé kí wọ́n ka ìwé ọdọọdún wa, 2012 Yearbook tán.
15 min: Àwọn ọ̀ràn tó ń fẹ́ àbójútó nínú ìjọ. Àsọyé lórí Àpéjọ Àgbègbè Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ọdún 2012.
Orin 14 àti Àdúrà