Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní May 14
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ MAY 14
Orin 33 àti Àdúrà
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
bt orí 20 ìpínrọ̀ 16 sí 20 (25 min.)
□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Jeremáyà 39-43 (10 min.)
No. 1: Jeremáyà 40:1-10 (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Ǹjẹ́ Àwọn Èèyàn Lè Wọnú Ìsinmi Ọlọ́run?—Heb. 4:10, 11 (5 min.)
No. 3: Àwọn Wo Ló Ń Lọ sí Ọ̀run?—td 33B (5 min.)
□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
5 min: Àwọn Ìfilọ̀.
15 min: Nípa Èyí Ni Gbogbo Ènìyàn Yóò Fi Mọ̀ Pé Ọmọ Ẹ̀yìn Mi Ni Yín. (Jòhánù 13:35) Ìjíròrò tó dá lórí Ilé Ìṣọ́ April 15, 2011, àpótí tó wà lójú ìwé 21, àti Ilé Ìṣọ́ January 15, 2010, ojú ìwé 15 sí 16, ìpínrọ̀ 19 àti 20. Ní kí àwọn ará sọ ẹ̀kọ́ tí wọ́n rí kọ́.
15 min: “Ẹ Máa Ṣọ́ra Tẹ́ ẹ Bá Wà Lóde Ẹ̀rí.” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Alábòójútó iṣẹ́ ìsìn ni kó bójú tó apá yìí. Sọ bí àwọn ará ṣe lè lo ohun tó wà nínú àpilẹ̀kọ yìí ní ìpínlẹ̀ ìwàásù ìjọ yín.
Orin 74 àti Àdúrà