Ẹ Máa Ṣọ́ra Tẹ́ ẹ Bá Wà Lóde Ẹ̀rí
1. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa ṣọ́ra tá a bá wà lóde ẹ̀rí?
1 ‘Gẹ́gẹ́ bí àgùntàn láàárín àwọn ìkookò,’ àwa ìránṣẹ́ Ọlọ́run ń wàásù “láàárín ìran oníwà wíwọ́ àti onímàgòmágó.” (Mát. 10:16; Fílí. 2:15) Àwọn ìròyìn tó ń bani lẹ́rù nípa àwọn tó ń da ìgboro rú, àwọn jàǹdùkú tó ń fa wàhálà, àtàwọn ajínigbé ti dèyí tó wọ́pọ̀, èyí tó fi hàn pé ńṣe ni àwọn èèyàn burúkú ń tẹ̀ síwájú “láti inú búburú sínú búburú jù.” (2 Tím. 3:13) Ìlànà Ìwé Mímọ́ wo la lè lò táá mú kí á “jẹ́ oníṣọ̀ọ́ra” tá a bá wà lóde ẹ̀rí?—Mát. 10:16.
2. Àwọn nǹkan wo ló lè mú kí ó bọ́gbọ́n mu pé ká fi ìpínlẹ̀ ìwàásù kan sílẹ̀ ká sì lọ wàásù níbòmíì?
2 Fọgbọ́n Hùwà: Òwe 22:3 jẹ́ ká mọ̀ pé ó bọ́gbọ́n mu pé ká ‘fi ara wa pa mọ́’ kí á má bàa ko sínú àjálù. Torí náà, máa wà lójúfò! Ipò nǹkan lè ṣàdédé yí pa dà láwọn àdúgbò tó jẹ́ pé kì í fi bẹ́ẹ̀ séwu tẹ́lẹ̀. O lè kíyè sí i pé àwọn ọlọ́pàá ń lọ wọ́n ń bọ̀ ní àwọn òpópónà kan tàbí kí èrò máa kóra jọ. Nígbà míì, onílé kan tó nífẹ̀ẹ́ wa lè kì wá nílọ̀. Dípò tí wàá fi máa dúró pé o fẹ́ mọ ohun tó ń ṣẹlẹ̀, ohun tó bọ́gbọ́n mu ni pé kó o tètè kúrò níbẹ̀, kó o sì lọ síbòmíì.—Òwe 17:14; Jòh. 8:59; 1 Tẹs. 4:11.
3. Báwo ni ìlànà tó wà nínú Oníwàásù 4:9 sè kan iṣẹ́ ìwàásù wa?
3 Má Ṣe Máa Dá Nìkan Ṣiṣẹ́: Oníwàásù 4:9 sọ pé, “Ẹni méjì sàn ju ẹnì kan.” Ó ti lè mọ́ ẹ lára pé kó o máa dá ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí láìséwu, àmọ́ ní báyìí, ṣé kò léwu pé kó o máa dá ṣiṣẹ́? Láwọn àdúgbò kan, kò léwu. Àmọ́, ní àwọn àdúgbò míì, kò bọ́gbọ́n mu pé kí arábìnrin kan tàbí ọ̀dọ́ kan máa dá ṣiṣẹ́ láti ilé dé ilé, pàápàá jù lọ lọ́wọ́ ìrọ̀lẹ́. Ìrírí fi hàn pé ààbò gidi ló jẹ́ téèyàn bá ń bá ẹnì kan tó wà lójúfò ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí. (Oníw. 4:10, 12) Ó dára kó o máa wà lójúfò láti mọ bí nǹkan ṣe ń lọ̀ sí fún àwọn tẹ́ ẹ jọ wà lóde ẹ̀rí. Jẹ́ kó mọ́ ẹ lára láti máa dágbére fún àwọn tẹ́ ẹ jọ wà lóde ẹ̀rí tó o bá fẹ́ fi ìpínlẹ̀ ìwàásù tẹ́ ẹ wà sílẹ̀.
4. Kí la lè ṣe láti dáàbò gbogbo àwọn tá a jọ wà nínú ìjọ?
4 Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé àwọn alàgbà ‘ń ṣọ́ ẹ̀ṣọ́ lórí ọkàn wa,’ ojúṣe wọn ni láti tọ́ wa sọ́nà níbàámu pẹ̀lú bí àwọn nǹkan ṣe rí ládùúgbò wa. (Héb. 13:17) Ó dájú pé Jèhófà máa bù kún wa tá a bá mọ̀wọ̀n ara wa, tá a sì fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú wọn. (Míkà 6:8; 1 Kọ́r. 10:12) Ǹjẹ́ kí gbogbo àwa ìránṣẹ́ Ọlọ́run máa ṣe ipa tiwa láti jẹ́rìí kúnnákúnná láwọn ìpínlẹ̀ wa, síbẹ̀ ká rí i pé tìṣọ́ratìṣọ́ra là ń ṣiṣẹ́ náà nígbà gbogbo.