Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní May 21
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ MAY 21
Orin 121 àti Àdúrà
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
bt orí 21 ìpínrọ̀ 1 sí 7, àti àpótí tó wà lójú ìwé 166 (25 min.)
□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Jeremáyà 44-48 (10 min.)
No. 1: Jeremáyà 46:18-28 (4 min. tàbí kò máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Àwọn Tó Máa Ní Ìyè Àìnípẹ̀kun Lórí Ilẹ̀ Ayé Kò Níye—td 33D (5 min.)
No. 3: Báwo La Ṣe Lè “Fúnrúgbìn Pẹ̀lú Níní Ẹ̀mí Lọ́kàn”?—Gál. 6:8 (5 min.)
□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
10 min: Àwọn Ìfilọ̀. Sọ ìwé tá a máa lò lóde ẹ̀rí lóṣù June, kó o sì ṣàṣefihàn ìgbékalẹ̀ kan.
15 min: Ẹ̀yin Ọ̀dọ́, Ǹjẹ́ Ẹ Lè Ṣe Iṣẹ́ Aṣáájú-ọ̀nà Olùrànlọ́wọ́ Lákòókò Ọlidé? Àsọyé. Ní ṣókí, sọ̀rọ̀ lórí àwọn ohun tí à ń béèrè lọ́wọ́ ẹni tó bá fẹ́ ṣe aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ bó ṣe wà ní ìpínrọ̀ 1 lójú ìwé 113 nínú ìwé A Ṣètò Wa, kó o sọ àwọn ohun tó lè jẹ́ kéèyàn tóótun láti ṣe aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́. Kó o wá fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu akéde kan tàbí méjì tí wọ́n ṣe aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ lákòókò ọlidé. Fún àwọn ọ̀dọ́ níṣìírí pé kí wọ́n ṣe aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ lákòókò ọlidé tó ń bọ̀ yìí.
10 min: “Ọ̀rọ̀ Tí Ọlọ́run Bá Wa Sọ Nípasẹ̀ Jeremáyà.” Ìbéèrè àti ìdáhùn.
Orin 41 àti Àdúrà