Àwọn Ìfilọ̀
◼ Ìwé tá a máa lò ní July àti August: Ẹ lo ọ̀kan lára àwọn ìwé pẹlẹbẹ olójú-ewé 32 wọ̀nyí: Tẹ́tí sí Ọlọ́run tàbí Tẹ́tí sí Ọlọ́run Kó O Lè Wà Láàyè Títí Láé, àti Ìwọ Lè Di Ọ̀rẹ́ Ọlọ́run! kẹ́ ẹ́ sì gbìyànjú láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Nígbà tẹ́ ẹ bá ń ṣe ìpadàbẹ̀wò, ẹ lè fún onílé ní ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni tàbí kẹ́ ẹ fún un ní ìwé pẹlẹbẹ èyíkéyìí tẹ́ ẹ bá rí i pé ó máa nífẹ̀ẹ́ sí. September àti October: Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! Nígbà tẹ́ ẹ bá ń ṣe ìpadàbẹ̀wò, ẹ lè fún onílé ní ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni tàbí kẹ́ ẹ fún un ní èyí tẹ́ ẹ bá rí i pé ó máa nífẹ̀ẹ́ sí nínú ìwé pẹlẹbẹ Tẹ́tí sí Ọlọ́run tàbí Tẹ́tí sí Ọlọ́run Kó O Lè Wà Láàyè Títí Láé, kẹ́ ẹ sì sapá láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú rẹ̀.
◼ Àwo orin tá a fi ẹnu kọ lédè Gẹ̀ẹ́sì, ìyẹn Sing to Jehovah—Vocal Renditions, Disc 5 máa jáde sórí ìkànnì jw.org ní August 1, ẹ sì lè wà á jáde. Ti èdè Gẹ̀ẹ́sì la máa kọ́kọ́ fi sórí ìkànnì náà, a ó wá fi ti àwọn èdè míì síbẹ̀ tó bá yá. Ẹ lè béèrè fún àwọn àwo CD aláfetígbọ́ nípasẹ̀ ìjọ yín. Nítorí pé owó tó máa ná yín láti wa àwọn ohun tẹ́ ẹ fẹ́ jáde látorí ìkànnì wa máa dín kù gan-an sí iye tó máa ń ná wa láti ṣe àwọn àwo jáde ká sì tún kó wọn ránṣẹ́, a rọ̀ yín pé kẹ́ ẹ máa wá àwọn ohun tẹ́ ẹ bá fẹ́ jáde lórí ìkànnì wa, tẹ́ ẹ bá lè ṣe bẹ́ẹ. A ti fi àwo 1 sí 4, tá a fẹnu kọ lédè Gẹ̀ẹ́sì, sórí ìkànnì náà tẹ́lẹ̀.