Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní August 6
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ AUGUST 6
Orin 60 àti Àdúrà
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
bt orí 24 ìpínrọ̀ 16 sí 21 (25 min.)
□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Ìsíkíẹ́lì 24-27 (10 min.)
No. 1: Ìsíkíẹ́lì 24:15-27 (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Gbogbo Kristẹni Ló Gbọ́dọ̀ Jẹ́ Òjíṣẹ́—td 37A (5 min.)
No. 3: Ǹjẹ́ Ìsíkíẹ́lì 18:20 Ta Ko Ẹ́kísódù 20:5? (5 min.)
□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
5 min: Àwọn Ìfilọ̀.
10 min: Ṣé O Ti Múra Sílẹ̀ Fún Sáà Tuntun Tó Máa Bẹ̀rẹ̀ Nílé Ẹ̀kọ́? Ìjíròrò. Ní kí àwọn ará sọ díẹ̀ lára àwọn ìṣòro táwọn ọ̀dọ́ tó jẹ́ Kristẹni máa ń bá pàdé níléèwé. Ṣàlàyé bí àwọn òbí ṣe lè lo ìwé atọ́ka, ìyẹn Index, Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé àti àwọn ìwé míì tí ètò Ọlọ́run ṣe, láti múra àwọn ọmọ wọn sílẹ̀ nígbà ìjọsìn ìdílé, kí wọ́n lè yẹra fún àwọn ohun tó lè dẹ wọ́n wò àti bí wọ́n ṣe lè ṣàlàyé ohun tí wọ́n gbà gbọ́. (1 Pét. 3:15) Yan kókó ọ̀rọ̀ kan tàbí méjì, kó o sì sọ díẹ̀ lára ohun tí àwọn ìtẹ̀jáde náà sọ tó lè wúlò fún wọn. Ní kí àwọn ará sọ bí wọ́n ṣe wàásù níléèwé.
10 min: Àwọn ọ̀ràn tó ń fẹ́ àbójútó nínú ìjọ.
10 min: Àwọn Àbá Tá A Lè Lò Láti Fi Ìwé Ìròyìn Lọni Lóṣù August. Ìjíròrò. Fi ààbọ̀ ìṣẹ́jú sí ìṣẹ́jú kan sọ ìdí táwọn èèyàn fi máa nífẹ̀ẹ́ sí àwọn ìwé ìròyìn wa ní ìpínlẹ̀ ìwàásù yín. Lẹ́yìn náà, lo àwọn àpilẹ̀kọ tó dá lórí àkòrí Ilé Ìṣọ́ oṣù August, ní kí àwọn ará sọ àwọn ìbéèrè tó lè mú kí àwọn èèyàn nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ wọn, kí wọ́n sì sọ ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí wọ́n lè fi ti ọ̀rọ̀ wọn lẹ́yìn. Ohun kan náà ni kó o ṣe nípa àwọn àpilẹ̀kọ tó dá lórí àkòrí Jí! July–September 2012, tí àkókò bá ṣì wà, ẹ tún lè jíròrò àpilẹ̀kọ mìíràn nínú ìwé ìròyìn méjèèjì. Ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè fi ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ìwé ìròyìn náà lọni.
Orin 97 àti Àdúrà