Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tá A Lè Lò
Láti Bẹ̀rẹ̀ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ní Sátidé Àkọ́kọ́ Lóṣù August
“Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ gbogbo èèyàn ló máa ń gbàdúrà. Kódà àwọn tí kò gba Ọlọ́run gbọ́ máa ń gbàdúrà tí wọ́n bá níṣòro. Ǹjẹ́ o rò pé gbogbo àdúrà ni Ọlọ́run ń gbọ́?” Jẹ́ kó fèsì. Fi ẹ̀yìn Ilé Ìṣọ́ August 1 hàn án, kẹ́ ẹ sì jọ jíròrò àlàyé tó dá lórí ìbéèrè àkọ́kọ́ àti ó kéré tán ọ̀kan lára àwọn ẹsẹ Bíbélì tó wà níbẹ̀. Fún un ní ìwé ìròyìn náà, kẹ́ ẹ sì jọ ṣàdéhùn ìgbà tí wàá pa dà lọ jíròrò ìbéèrè tó kàn.
Àkíyèsí: Kí ẹ ṣe àṣefihàn ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ yìí ní ìpàdé fún iṣẹ́ ìsìn pápá tẹ́ ẹ máa ṣe ní August 3.
Ilé Ìṣọ́ August 1
“À ń bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ nípa bí àwọn ohun tó ń mú ọkàn fà sí ìṣekúṣe ṣe gbòde kan lónìí. Àmọ́ ọ̀pọ̀ èèyàn ló rò pé kò sí ohun tó burú nínú bó ṣe wà káàkiri. Kí lèrò tìẹ? [Jẹ́ kó fèsì.] Jésù sọ pé èso tí igi kan so la fi ń mọ irú igi tó jẹ́. [Ka Mátíù 7:17.] Ìwé ìròyìn yìí ṣàlàyé àwọn ìṣòro tí àwọn ohun tó ń mú ọkàn fà sí ìṣekúṣe máa ń fà. Ó sì tún jẹ́ ká mọ ohun téèyàn lè ṣe láti jáwọ́ nínú rẹ̀.”
Jí! July–August
“Ẹ jẹ́ mọ̀ pé bí ẹni tó ń ṣàkóso ayé yìí ṣe burú náà ni ìwà àwọn èèyàn ṣe burú tó. Àmọ́, ṣé o mọ ẹni tó ń ṣàkóso ayé yìí? [Jẹ́ kó fèsì.] Gbọ́ ohun tí Ọlọ́run máa ṣe láti fòpin sí ìṣàkóso Sátánì. [Ka Jòhánù 12:31.] Ìwé ìròyìn yìí tú àṣírí irú ẹni tí Sátánì jẹ́ gan-an. Ó sì tún sọ àwọn ohun tá a lè ṣe láti dáàbò bo ara wa lọ́wọ́ àwọn ètekéte rẹ̀.” Fi àpilẹ̀kọ tó bẹ̀rẹ̀ lójú ìwé 14 hàn án.