Àwọn Kókó Inú Ìròyìn Iṣẹ́ Ìsìn
Láàárín oṣù July àti November ọdún 2010, àwọn akéde tí iye wọn jẹ́ ọ̀rìndínlẹ́gbẹ̀rin ó lé méjì [922] láti ìjọ méjìdínláàádọ́rùn-ún [88] ló lọ wàásù ní àwọn ìpínlẹ̀ tí a kò yàn fúnni àti àwọn ìpínlẹ̀ tí a kì í ṣe déédéé ní Nàìjíríà. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ àwọn èèyàn tí iye wọn jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ó lé ọ̀ọ́dúnrún àti méjìléláàádọ́ta [3,352] lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ni àwọn ìpínlẹ̀ tí wọ́n lọ. Ọkùnrin kan tó gba ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni sọ pé orí keje lòun ti fẹ́ bẹ̀rẹ̀, torí pé ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ọkùnrin àti bàbá rẹ̀ kú ní oṣù August ọdún 2010. Ó sọ pé òun fẹ́ ka orí náà tán kí àwọn akéde náà tó kúrò ní ìpínlẹ̀ yẹn, torí pé àwọn ohun tó wà níbẹ̀ tù ú nínú ó sì jẹ́ kó ní ìrètí tó dájú. Àkókò tún ti tó báyìí o láti jáde lọ tu àwọn èèyàn nínú láàárín àkókò tá a máa lọ fi wàásù lọ́nà àkànṣe ní àwọn ìpínlẹ̀ tí a kò yàn fúnni àti àwọn ìpínlẹ̀ tí a kì í ṣe déédéé. Ǹjẹ́ ìwọ náà lè lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ tó ṣe pàtàkì gan-an yìí?